Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 30:12-20 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Kì í ṣe òkè ọ̀run ni ó wà, tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo gun òkè ọ̀run lọ, tí yóo lọ bá wa mú un sọ̀kalẹ̀ wá, kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’

13. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní òdìkejì òkun tí ẹ óo fi wí pé, ‘Ta ni yóo la òkun kọjá fún wa, tí yóo lọ bá wa mú un wá kí á lè gbọ́ kí á sì pa á mọ́?’

14. Ṣugbọn nítòsí yín ni ọ̀rọ̀ náà wà, ó wà lẹ́nu yín, ó sì wà ninu ọkàn yín, tí ó fi jẹ́ pé ẹ lè ṣe é.

15. “Wò ó, mo gbé ikú ati ìyè kalẹ̀ níwájú yín lónìí, bákan náà ni mo sì gbé ire ati ibi kalẹ̀.

16. Tí ẹ bá pa òfin OLUWA Ọlọrun yín mọ́ bí mo ti fun yín lónìí, tí ẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, tí ẹ̀ ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀, tí ẹ sì ń pa àwọn òfin, ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, ẹ óo wà láàyè, ẹ óo sì máa pọ̀ sí i. OLUWA Ọlọrun yín yóo bukun yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà tí yóo sì di tiyín.

17. Ṣugbọn bí ọkàn yín bá yipada, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò gbọ́ tirẹ̀, tí ẹ bá jẹ́ kí wọn fà yín lọ bọ àwọn oriṣa, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,

18. mo wí fun yín gbangba lónìí pé, ẹ óo parun. Ẹ kò ní pẹ́ rárá lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gòkè Jọdani lọ gbà, tí yóo sì di tiyín.

19. Mo fi ilẹ̀ ati ọ̀run ṣe ẹlẹ́rìí níwájú yín lónìí, pé mo fun yín ní anfaani láti yan ikú tabi ìyè, ati láti yan ibukun tabi ègún. Nítorí náà, ẹ yan ìyè kí ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lè wà láàyè.

20. Ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀, kí ẹ sì máa súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ lè pẹ́ láyé, kí ẹ sì lè máa gbé orí ilẹ̀ tí OLUWA búra láti fún àwọn baba yín, àní Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu.”

Ka pipe ipin Diutaronomi 30