Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 28:32-44 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Àwọn ọmọ yín ọkunrin ati àwọn ọmọ yín obinrin óo di ti ẹni ẹlẹ́ni. Ẹ óo retí wọn títí, ẹ kò ní gbúròó wọn, kò sì ní sí ohunkohun tí ẹ lè ṣe sí i.

33. Orílẹ̀-èdè tí ẹ kò mọ̀ rí ni yóo jẹ ohun ọ̀gbìn yín ati gbogbo làálàá yín ní àjẹrun. Ìnilára ati ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ni ẹ óo máa rí nígbà gbogbo,

34. tóbẹ́ẹ̀ tí ohun tí ẹ óo máa fi ojú yín rí yóo yà yín ní wèrè.

35. OLUWA yóo da oówo burúkú bò yín lẹ́sẹ̀ ati lórúnkún, yóo burú tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní lè wò yín sàn. Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín títí dé àtàrí yín kìkì oówo ni yóo jẹ́.

36. “OLUWA yóo lé ẹ̀yin ati ẹni tí ẹ bá fi jọba yín lọ sí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí, ẹ óo sì máa bọ oríṣìíríṣìí oriṣa tí wọ́n fi igi ati òkúta gbẹ́ níbẹ̀.

37. Ẹ óo di ẹni ìríra, ẹni àmúpòwe ati ẹni ẹ̀sín, láàrin gbogbo àwọn eniyan, níbi tí OLUWA yóo le yín lọ.

38. “Ọpọlọpọ èso ni ẹ óo máa gbìn sinu oko yín, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ óo máa rí ká, nítorí eṣú ni yóo máa jẹ wọ́n.

39. Ẹ óo gbin ọgbà àjàrà, ẹ óo sì tọ́jú rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò ní rí èso rẹ̀ ká, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní mu ninu ọtí rẹ̀, nítorí pé àwọn kòkòrò yóo ti jẹ ẹ́.

40. Gbogbo ilẹ̀ yín yóo kún fún igi olifi, ṣugbọn ẹ kò ní rí òróró fi pa ara, nítorí pé rírẹ̀ ni èso olifi yín yóo máa rẹ̀ dànù.

41. Ẹ óo bí ọpọlọpọ ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn wọn kò ní jẹ́ tiyín, nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kó lẹ́rú lọ.

42. Gbogbo igi yín ati gbogbo èso ilẹ̀ yín ni yóo di ti àwọn eṣú.

43. “Àwọn àlejò tí wọ́n wà láàrin yín yóo máa níláárí jù yín lọ, ọwọ́ wọn yóo máa ròkè, ṣugbọn ní tiyín, ẹ óo di ẹni ilẹ̀ patapata.

44. Ọwọ́ àlejò yín ni ẹ óo ti máa tọrọ nǹkan, àwọn kò sì ní tọrọ ohunkohun lọ́wọ́ yín. Àwọn ni wọn yóo jẹ́ orí fun yín, ẹ̀yin yóo sì jẹ́ ìrù fún wọn.

Ka pipe ipin Diutaronomi 28