Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 17:7-18 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Àwọn ẹlẹ́rìí ni wọ́n gbọdọ̀ kọ́kọ́ sọ òkúta lu ẹni náà, lẹ́yìn náà ni gbogbo eniyan yóo tó kó òkúta bò ó, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín.

8. “Bí ẹjọ́ kan bá ta kókó tí ó ní àríyànjiyàn ninu, tí ó sì ṣòro láti dá fún àwọn onídàájọ́ yín, kì báà jẹ mọ́ ṣíṣèèṣì paniyan ati mímọ̀ọ́nmọ̀ paniyan, tabi ẹ̀tọ́ lórí ohun ìní ẹni; tabi tí ẹnìkan bá ṣe ohun àbùkù kan sí ẹlòmíràn, ẹ óo lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín yóo yàn, pé kí ẹ ti máa jọ́sìn.

9. Ẹ tọ àwọn alufaa ọmọ Lefi lọ, kí ẹ sì kó ẹjọ́ yín lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó wà ní ipò onídàájọ́ ní àkókò náà. Ẹ ro ẹjọ́ yín fún wọn, wọn yóo sì bá yín dá a.

10. Ohunkohun tí wọ́n bá sọ fun yín ní ibi tí OLUWA bá yàn ni ẹ gbọdọ̀ ṣe. Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá ní kí ẹ ṣe.

11. Ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fun yín ni kí ẹ gbà, kí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà tí wọ́n bá là sílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ yà sí ọ̀tún tabi sí òsì ninu ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fun yín.

12. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe oríkunkun sí ẹni tí ó jẹ́ onídàájọ́ nígbà náà, tabi alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà, pípa ni kí ẹ pa á; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ohun burúkú náà kúrò láàrin Israẹli.

13. Gbogbo àwọn eniyan ni yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo bà wọ́n; ẹnikẹ́ni kò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

14. “Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ bá gbà á, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ bá wí nígbà náà pé, ‘A óo fi ẹnìkan jọba lórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yí wa ká,’

15. ẹ lè fi ẹnikẹ́ni tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn fun yín jọba, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín ni ẹ gbọdọ̀ fi jọba, ẹ kò gbọdọ̀ fi àlejò, tí kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín jọba.

16. Ṣugbọn kò gbọdọ̀ máa kó ẹṣin jọ fún ara rẹ̀ tabi kí ó mú kí àwọn eniyan náà pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti láti ra ẹṣin kún ẹṣin, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti wí fun yín pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ sí ibẹ̀ mọ́.’

17. Kò gbọdọ̀ kó aya jọ kí ọkàn rẹ̀ má baà yipada; bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kó wúrà ati fadaka jọ fún ara rẹ̀.

18. “Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó gba ìwé òfin yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa ọmọ Lefi, kí ó dà á kọ sinu ìwé kan fún ara rẹ̀.

Ka pipe ipin Diutaronomi 17