Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 14:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ọmọ ni ẹ jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara yín lára tabi kí ẹ fá irun yín níwájú nígbà tí ẹ bá ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tí ó kú.

2. Nítorí pé, ẹni ìyàsọ́tọ̀ ni yín fún OLUWA Ọlọrun yín, OLUWA ti yàn yín láti jẹ́ eniyan tirẹ̀ láàrin gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé.

3. “Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ ohun ìríra.

4. Àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ nìwọ̀nyí: mààlúù, aguntan,

5. ewúrẹ́, àgbọ̀nrín ati èsúó ati ìgalà, ati oríṣìí ẹranko igbó kan tí ó dàbí ewúrẹ́, ati ẹranko kan tí wọn ń pè ní Pigarigi, ati ẹfọ̀n, ati ẹtu.

6. Àwọn ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji, tabi tí wọ́n bá ní ìka ẹsẹ̀, tí wọ́n sì ń jẹ àpọ̀jẹ, irú wọn ni kí ẹ máa jẹ.

7. Ṣugbọn ninu àwọn ẹran tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ ati àwọn tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji tabi tí wọ́n ní ìka ẹsẹ̀, àwọn wọnyi ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: ràkúnmí, ati ehoro ati ẹranko kan tí ó dàbí gara. Àwọn wọnyi ń jẹ àpọ̀jẹ lóòótọ́, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ wọn kò là, nítorí náà, wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín.

8. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹlẹ́dẹ̀, lóòótọ́ ó ní ìka ẹsẹ̀, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, nítorí náà, ó jẹ́ aláìmọ́ fun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fara kan òkú wọn.

9. “Ninu gbogbo àwọn abẹ̀mí tí ó wà ninu omi, àwọn wọnyi ni kí ẹ máa jẹ: gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ.

10. Ṣugbọn èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n, nítorí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín.

Ka pipe ipin Diutaronomi 14