Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 12:16-32 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ẹ̀jẹ̀ wọn nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí ẹni da omi.

17. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ninu ohun tí o bá jẹ́ ìdámẹ́wàá yín ninu ìlú yín, kì báà ṣe ìdámẹ́wàá ọkà yín, tabi ti ọtí waini, tabi ti òróró, tabi ti àkọ́bí mààlúù, tabi ti ewúrẹ́, tabi ti aguntan, tabi ohunkohun tí ẹ bá fi san ẹ̀jẹ́ fún OLUWA, tabi ọrẹ àtinúwá yín tabi ọrẹ àkànṣe yín.

18. Níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn, ni kí ẹ ti jẹ ẹ́; ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín, lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wà ninu ìlú yín. Kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.

19. Kí ẹ rí i dájú pé, ẹ kò gbàgbé àwọn ọmọ Lefi níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ yín.

20. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú kí ilẹ̀ yín pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, tí ẹran bá wù yín jẹ, ẹ lè jẹ ẹran dé ibi tí ó bá wù yín.

21. Bí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun bá jìnnà pupọ sí yín, ẹ mú mààlúù tabi aguntan láti inú agbo ẹran tí OLUWA fi fun yín, kí ẹ pa á bí mo ti pa á láṣẹ fun yín, kí ẹ sì jẹ ohunkohun tí ọkàn yín bá fẹ́ láti jẹ láàrin àwọn ìlú yín.

22. Ati ẹni tí ó mọ́ ati ẹni tí kò mọ́ ni ó lè jẹ ninu ẹran náà bí ìgbà tí eniyan ń jẹ ẹran ẹtu tabi ti àgbọ̀nrín.

23. Kí ẹ rí i dájú pé ẹ kò jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nítorí pé ninu ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí wà, ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran pẹlu ẹ̀mí rẹ̀.

24. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.

25. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín nígbà tí ẹ bá ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú OLUWA.

26. Ẹ gbọdọ̀ mú àwọn ohun ìyàsímímọ́ tí ẹ ní, ati àwọn ẹ̀jẹ́ yín lọ sí ibi tí OLUWA ti yàn fún ìrúbọ.

27. Kí ẹ rú ẹbọ sísun yín ati ẹran ati ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, ẹ da ẹ̀jẹ̀ ẹbọ yín sórí pẹpẹ OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì jẹ ara ẹran rẹ̀.

28. Ẹ kíyèsára, kí ẹ rí i dájú pé ẹ pa àwọn ohun tí mo pa láṣẹ fun yín mọ́, kí ó lè dára fún ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín títí lae.

29. “Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá pa àwọn orílẹ̀-èdè run níbi gbogbo tí ẹ bá lọ, tí ẹ bá bá wọn jagun tí ẹ gba ilẹ̀ wọn, tí ẹ sì ń gbé ibẹ̀;

30. ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà ṣìnà, lẹ́yìn tí Ọlọrun bá ti pa wọ́n run tán, kí ẹ má baà bèèrè pé, ‘Báwo ni àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi ṣe ń bọ àwọn oriṣa wọn? Kí àwa náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀.’

31. Ẹ kò gbọdọ̀ sin OLUWA Ọlọrun yín bí wọn ti ń bọ àwọn oriṣa wọn nítorí oríṣìíríṣìí ohun tí ó jẹ́ ìríra lójú OLUWA ni wọ́n máa ń ṣe. Wọn a máa fi àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn rúbọ sí oriṣa wọn.

32. “Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fun yín ni kí ẹ fọkàn sí, kí ẹ sì ṣe é, ẹ kò gbọdọ̀ fi kún un, ẹ kò sì gbọdọ̀ mú kúrò ninu rẹ̀.

Ka pipe ipin Diutaronomi 12