Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 1:30-46 BIBELI MIMỌ (BM)

30. OLUWA Ọlọrun yín tí ń ṣáájú yín ni yóo jà fun yín, gẹ́gẹ́ bí ó ti jà fun yín ní ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ̀yin náà sì fi ojú ara yín rí i.

31. Ninu aṣálẹ̀ ńkọ́? Ṣebí ẹ rí i bí OLUWA Ọlọrun yín ti gbé yín, bí baba tíí gbé ọmọ rẹ̀, ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ tọ̀ títí tí ẹ fi dé ibi tí ẹ wà yìí.

32. Sibẹsibẹ ẹ kò gba OLUWA Ọlọrun yín gbọ́,

33. Ọlọrun tí ń lọ níwájú yín ninu ọ̀wọ̀n iná lóru, ati ninu ìkùukùu lọ́sàn-án, láti fi ọ̀nà tí ẹ óo máa tọ̀ hàn yín kí ó lè bá yín wá ibi tí ẹ óo pàgọ́ yín sí.

34. “OLUWA gbọ́ ohun tí ẹ sọ, inú bí i, ó sì búra pé,

35. ẹnikẹ́ni ninu ìran burúkú náà kò ní fi ojú kan ilẹ̀ dáradára tí òun ti búra pé òun óo fún àwọn baba yín;

36. àfi Kalebu ọmọ Jefune ni yóo rí i. Òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ni òun óo sì fún ní ilẹ̀ tí ó ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ̀, nítorí pé, ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé òun.

37. OLUWA bínú sí èmi pàápàá nítorí tiyín, ó ní èmi náà kò ní dé ibẹ̀.

38. Joṣua, ọmọ Nuni, tí ń ṣe iranṣẹ òun, ni yóo dé ilẹ̀ náà. Nítorí náà, ó ní kí n mú un lọ́kàn le, nítorí òun ni yóo jẹ́ kí Israẹli gba ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì jogún rẹ̀.

39. Ọlọrun ní àwọn ọmọ yín kéékèèké, tí kò tíì mọ ire yàtọ̀ sí ibi, àwọn tí ẹ sọ pé wọn yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín, àwọn ni wọn yóo dé ilẹ̀ náà, àwọn ni òun óo sì fi fún, ilẹ̀ náà yóo sì di ìní wọn.

40. Ṣugbọn ní tiyín, ó ní kí ẹ yipada, kí ẹ sì máa lọ sinu aṣálẹ̀, ní apá ọ̀nà Òkun Pupa.

41. “Nígbà náà, ẹ dá mi lóhùn, ẹ ní, ẹ ti ṣẹ̀ sí OLUWA, nítorí náà, ẹ óo dìde, ẹ óo sì lọ jagun, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun ti pa á láṣẹ fun yín. Olukuluku yín bá múra láti jagun, gbogbo èrò yín nígbà náà ni pé kò ní ṣòro rárá láti ṣẹgun àwọn tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà.

42. “OLUWA wí fún mi pé, ‘Kìlọ̀ fún wọn kí wọ́n má gòkè lọ jagun, nítorí pé n kò ní bá wọn lọ; bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwọn ọ̀tá yóo ṣẹgun wọn.’

43. Mo sọ ohun tí OLUWA wí fun yín, ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́. Ẹ ṣe oríkunkun sí àṣẹ OLUWA, ẹ sì lọ pẹlu ẹ̀mí ìgbéraga.

44. Àwọn ará Amori tí wọn ń gbé agbègbè olókè náà bá jáde sí yín, wọ́n le yín bí oyin tíí lé ni, wọ́n sì pa yín ní ìpakúpa láti Seiri títí dé Horima.

45. Nígbà tí ẹ pada dé, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí sọkún níwájú OLUWA, ṣugbọn OLUWA kò gbọ́ tiyín, bẹ́ẹ̀ ni kò fetí sí ẹkún yín.

46. “Nítorí náà, gbogbo wa wà ní Kadeṣi fún ìgbà pípẹ́.

Ka pipe ipin Diutaronomi 1