Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 2:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún keji tí Nebukadinesari gun orí oyè, ó lá àwọn àlá kan; àlá náà bà á lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi lè sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà.

2. Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó ati àwọn ará Kalidea jọ, kí wọ́n wá rọ́ àlá òun fún òun. Gbogbo wọn sì wá siwaju ọba.

3. Ọba sọ fún wọn pé, “Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù pupọ, mo sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

4. Àwọn ará Kalidea bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ọba pẹ́! Rọ́ àlá rẹ fún àwa iranṣẹ rẹ, a óo sì túmọ̀ rẹ̀.”

5. Ṣugbọn ọba dá wọn lóhùn, pé, “Ohun tí mo bá sọ abẹ ni ó gé e; bí ẹ kò bá lè rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fà yín ya ní tapá-titan, ilé yín yóo sì di àlàpà.

6. Ṣugbọn bí ẹ bá rọ́ àlá náà, tí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹ óo gba ẹ̀bùn, ìdálọ́lá ati ẹ̀yẹ ńlá, nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

7. Wọ́n dá ọba lóhùn lẹẹkeji pé, “Kí kabiyesi rọ́ àlá rẹ̀ fún wa, a óo sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

8. Ọba dá wọn lóhùn pé, “Mo mọ̀ dájú pé ẹ kàn fẹ́ máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò ni, nítorí ẹ ti mọ̀ pé bí mo ti wí ni n óo ṣe.

9. Bí ẹ kò bá rọ́ àlá mi fún mi, ìyà kanṣoṣo ni n óo fi jẹ yín. Gbogbo yín ti gbìmọ̀ pọ̀ láti máa parọ́, ati láti máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò. Ẹ rọ́ àlá mi fún mi, n óo sì mọ̀ dájú pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

10. Wọ́n dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ẹni náà láyé yìí, tí ó lè sọ ohun tí kabiyesi fẹ́ kí á sọ, kò sí ọba ńlá tabi alágbára kankan tí ó tíì bèèrè irú nǹkan yìí lọ́wọ́ pidánpidán kan, tabi lọ́wọ́ àwọn aláfọ̀ṣẹ, tabi lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea rí.

11. Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.”

12. Nítorí náà inú ọba ru, ó sì bínú gidigidi, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run.

Ka pipe ipin Daniẹli 2