Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 11:23-41 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Yóo máa fi ẹ̀tàn bá àwọn orílẹ̀-èdè dá majẹmu. Yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbilẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí ó jọba lé lórí kéré.

24. Lójijì yóo wá sí àwọn ibi tí ó ní ọrọ̀ jùlọ ní agbègbè náà, yóo máa ṣe ohun tí àwọn baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí. Yóo máa pín ìkógun rẹ̀ fún wọn. Yóo máa wá ọ̀nà ti yóo fi gba àwọn ìlú olódi; ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ni.

25. “Yóo fi gbogbo agbára ati ìgboyà rẹ̀ gbé ogun ńlá ti ọba Ijipti; ọba Ijipti náà yóo gbé ogun ńlá tì í, ṣugbọn kò ní lè dúró níwájú ọba Ijipti nítorí pé wọn yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn.

26. Àwọn tí wọ́n ń bá a jẹ oúnjẹ àdídùn pọ̀ gan-an ni yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn; gbogbo ogun rẹ̀ ni yóo túká, ọpọlọpọ yóo sì kú.

27. Àwọn ọba mejeeji ni yóo pinnu láti hùwà àrékérekè, wọn ó sì máa purọ́ tan ara wọn jẹ níbi tí wọ́n ti jọ ń jẹun; ṣugbọn òfo ni ọgbọ́n àrékérekè wọn yóo já sí; nítorí pé òpin wọn yóo dé ní àkókò tí a ti pinnu.

28. Ọba Siria yóo wá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹlu gbogbo ìkógun rẹ̀. Ṣugbọn yóo pinnu ní ọkàn rẹ̀ láti gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli. Nígbà tí ó bá ṣe bí ó ti fẹ́ tán, yóo pada sí ilẹ̀ rẹ̀.

29. “Ní àkókò tí a ti pinnu, yóo tún gbógun ti ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn nǹkan kò ní rí bíi ti àkọ́kọ́ fún un;

30. nítorí pé, àwọn ọmọ ogun Kitimu tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ ojú omi yóo gbógun tì í.“Ẹ̀rù yóo bà á, yóo sì sá pada, yóo fi ibinu ńlá gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli, yóo sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn tí wọ́n ti kọ majẹmu náà sílẹ̀.

31. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo wá, wọn yóo sọ Tẹmpili ati ibi ààbò di aláìmọ́, wọn yóo dáwọ́ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo dúró, wọn yóo sì gbé ohun ìríra tíí fa ìsọdahoro kalẹ̀.

32. Pẹlu ẹ̀tàn, ọba yìí yóo mú àwọn tí wọ́n kọ majẹmu náà sílẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́; ṣugbọn àwọn tí wọ́n mọ Ọlọrun yóo dúró ṣinṣin, wọn óo sì ṣe ẹ̀tọ́.

33. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n láàrin wọn óo máa la ọpọlọpọ lọ́yẹ, ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀, wọn óo kú ikú idà, a óo dáná sun wọ́n, a óo kó wọn lẹ́rù, a óo sì kó wọn ní ẹrú lọ.

34. Nígbà tí a bá ṣẹgun wọn, wọn yóo rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ gbà, ọpọlọpọ yóo sì faramọ́ wọn pẹlu ẹ̀tàn.

35. Díẹ̀ ninu àwọn ọlọ́gbọ́n yóo kú lójú ogun, a óo fi dán àwọn ọmọ Israẹli wò láti wẹ̀ wọ́n mọ́ ati láti mú gbogbo àbààwọ́n wọn kúrò títí di àkókò ìkẹyìn, ní àkókò tí Ọlọrun ti pinnu.

36. “Ohun tí ó bá wu ọba náà ni yóo máa ṣe; yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo oriṣa lọ, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo máa sọ̀rọ̀ tó lòdì sí Ọlọrun àwọn ọlọrun, yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i títí ọjọ́ ibinu tí a dá fún un yóo fi pé; nítorí pé ohun tí Ọlọrun ti pinnu yóo ṣẹ.

37. Kò ní náání oriṣa tí àwọn baba rẹ̀ ń sìn, kò sì ní bìkítà fún èyí tí àwọn obinrin fẹ́ràn; kò ní bìkítà fún oriṣa kankan, nítorí pé yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ.

38. Dípò gbogbo wọn, yóo máa bọ oriṣa àwọn ìlú olódi; oriṣa tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ rí ni yóo máa sìn, yóo máa fún un ní wúrà ati fadaka, òkúta iyebíye ati àwọn ẹ̀bùn olówó iyebíye.

39. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn tí ń bọ oriṣa àjèjì kan, yóo bá àwọn ìlú olódi tí wọ́n lágbára jùlọ jà. Yóo bu ọlá fún àwọn tí wọ́n bá yẹ́ ẹ sí. Yóo fi wọ́n jẹ olórí ọpọlọpọ eniyan; yóo sì fi ilẹ̀ ṣe ẹ̀bùn fún àwọn tí wọ́n bá fún un lówó.

40. “Nígbà tí àkókò ìkẹyìn bá dé, ọba ilẹ̀ Ijipti yóo gbógun tì í; ṣugbọn ọba Siria yóo gbógun tì í bí ìjì líle, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi. Yóo kọlu àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ lọ bí àgbàrá òjò.

41. Yóo wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Ẹgbẹẹgbẹrun yóo ṣubú, ṣugbọn a óo gba Edomu ati Moabu lọ́wọ́ rẹ̀, ati ibi tí ó ṣe pataki jùlọ ninu ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

Ka pipe ipin Daniẹli 11