Ọba Siria yóo wá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹlu gbogbo ìkógun rẹ̀. Ṣugbọn yóo pinnu ní ọkàn rẹ̀ láti gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli. Nígbà tí ó bá ṣe bí ó ti fẹ́ tán, yóo pada sí ilẹ̀ rẹ̀.