Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 21:4-10 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ahabu bá pada lọ sílé pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ati ibinu, nítorí ohun tí Naboti ará Jesireeli wí fún un. Ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó kọjú sí ògiri, kò sì jẹun.

5. Jesebẹli, aya rẹ̀, wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Kí ló dé tí ọkàn rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì tóbẹ́ẹ̀ tí o kò fi jẹun?”

6. Ahabu dá a lóhùn pé, “Mo sọ fún Naboti pé mo fẹ́ ra ọgbà àjàrà rẹ̀, tabi bí ó bá fẹ́, kí ó jẹ́ kí n fún un ni òmíràn dípò rẹ̀; ṣugbọn ó ní òun kò lè fún mi ní ọgbà àjàrà òun.”

7. Jesebẹli, aya rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Họ́wù! Ṣebí ìwọ ni ọba Israẹli, àbí ìwọ kọ́? Dìde nílẹ̀ kí o jẹun, kí o sì jẹ́ kí inú rẹ dùn, n óo gba ọgbà àjàrà Naboti fún ọ.”

8. Jesebẹli bá kọ ìwé ní orúkọ Ahabu, ó fi òǹtẹ̀ Ahabu tẹ̀ ẹ́, ó fi ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà ati àwọn eniyan ńláńlá ní ìlú tí Naboti ń gbé.

9. Ohun tí ó kọ sinu ìwé náà ni pé, “Ẹ kéde ọjọ́ ààwẹ̀ kan, ẹ pe àwọn eniyan jọ, ẹ sì fi Naboti jókòó ní ipò ọlá.

10. Kí ẹ wá àwọn eniyankeniyan meji kan tí wọ́n ya aṣa, kí wọ́n jókòó níwájú rẹ̀, kí wọ́n sì fi ẹ̀sùn kàn án pé, ó bú Ọlọrun ati ọba. Lẹ́yìn náà, ẹ mú un jáde sẹ́yìn odi ìlú, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 21