Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 21:2-8 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ní ọjọ́ kan, Ahabu pe Naboti ó ní, “Fún mi ni ọgbà àjàrà rẹ, mo fẹ́ lo ilẹ̀ náà fún ọgbà ewébẹ̀ nítorí ó súnmọ́ tòsí ààfin mi. N óo fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó dára ju èyí lọ dípò rẹ̀, tabi tí ó bá sì wù ọ́, n óo san owó rẹ̀ fún ọ.”

3. Naboti dáhùn pé, “Ọwọ́ àwọn baba ńlá mi ni mo ti jogún ọgbà àjàrà yìí; OLUWA má jẹ́ kí n rí ohun tí n óo fi gbé e fún ọ.”

4. Ahabu bá pada lọ sílé pẹlu ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn ati ibinu, nítorí ohun tí Naboti ará Jesireeli wí fún un. Ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó kọjú sí ògiri, kò sì jẹun.

5. Jesebẹli, aya rẹ̀, wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bi í pé, “Kí ló dé tí ọkàn rẹ fi rẹ̀wẹ̀sì tóbẹ́ẹ̀ tí o kò fi jẹun?”

6. Ahabu dá a lóhùn pé, “Mo sọ fún Naboti pé mo fẹ́ ra ọgbà àjàrà rẹ̀, tabi bí ó bá fẹ́, kí ó jẹ́ kí n fún un ni òmíràn dípò rẹ̀; ṣugbọn ó ní òun kò lè fún mi ní ọgbà àjàrà òun.”

7. Jesebẹli, aya rẹ̀ dá a lóhùn pé, “Họ́wù! Ṣebí ìwọ ni ọba Israẹli, àbí ìwọ kọ́? Dìde nílẹ̀ kí o jẹun, kí o sì jẹ́ kí inú rẹ dùn, n óo gba ọgbà àjàrà Naboti fún ọ.”

8. Jesebẹli bá kọ ìwé ní orúkọ Ahabu, ó fi òǹtẹ̀ Ahabu tẹ̀ ẹ́, ó fi ranṣẹ sí àwọn àgbààgbà ati àwọn eniyan ńláńlá ní ìlú tí Naboti ń gbé.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 21