Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 19:3-15 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ẹ̀rù ba Elija, ó sì sá fún ikú. Ó lọ sí Beeriṣeba, ní ilẹ̀ Juda.Ó fi iranṣẹ rẹ̀ sibẹ,

4. ṣugbọn òun alára wọ inú ijù lọ ní ìrìn odidi ọjọ́ kan kí ó tó dúró. Ó bá jókòó lábẹ́ ìbòòji igi kan, ó wo ara rẹ̀ bíi kí òun kú. Ó sì gbadura sí OLUWA pé, “OLUWA, ó tó gẹ́ẹ́ báyìí! Kúkú pa mí. Kí ni mo fi sàn ju àwọn baba mi lọ?”

5. Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi náà, ó sì sùn. Lójijì, angẹli kan fi ọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé, “Dìde kí o jẹun.”

6. Ó wò yíká, ó sì rí ìṣù àkàrà kan, ati ìkòkò omi kan lẹ́bàá ìgbèrí rẹ̀. Ó jẹun, ó mu omi, ó sì tún dùbúlẹ̀.

7. Angẹli OLUWA náà pada wa, ó jí i, ó sì wí fún un pé, “Dìde kí o jẹun, kí ìrìn àjò náà má baà pọ̀jù fún ọ.”

8. Elija dìde, ó jẹun, ó sì tún mu omi. Oúnjẹ náà sì fún un ní agbára láti rìn fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru títí tí ó fi dé orí òkè Horebu, òkè Ọlọrun.

9. Ó dé ibi ihò àpáta kan, ó sì sùn níbẹ̀ mọ́jú ọjọ́ keji.OLUWA bá a sọ̀rọ̀, ó bi í pé, “Elija, kí ni ò ń ṣe níhìn-ín?”

10. Elija dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí ìwọ OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti kọ majẹmu rẹ tì, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.”

11. OLUWA wí fún un pé, “Lọ dúró níwájú mi ní orí òkè yìí.” OLUWA ba kọjá lọ, ẹ̀fúùfù líle kán fẹ́, ó la òkè náà, ó sì fọ́ àwọn òkúta rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ níwájú OLUWA. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu ẹ̀fúùfù líle náà. Lẹ́yìn ẹ̀fúùfù náà, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹ̀, gbogbo ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mì tìtì. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

12. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, iná ńlá kan bẹ̀rẹ̀ sí jó. Ṣugbọn OLUWA kò sí ninu iná náà. Lẹ́yìn iná náà, ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kan rọra sọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́.

13. Nígbà tí Elija gbọ́ ohùn náà, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ bojú, ó jáde, ó sì dúró ní ẹnu ọ̀nà ihò àpáta náà. Ohùn kan bi í pé, “Elija, kí ni ò ń ṣe níhìn-ín?”

14. Ó bá dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti da majẹmu rẹ̀, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ̀. Èmi nìkan ṣoṣo, ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.”

15. OLUWA dá a lóhùn pé, “Pada lọ sinu aṣálẹ̀ ẹ̀bá Damasku. Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, fi àmì òróró yan Hasaeli ní ọba Siria.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 19