Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 14:14-23 BIBELI MIMỌ (BM)

14. OLUWA yóo fi ẹnìkan jọba lórí Israẹli tí yóo run ìdílé Jeroboamu lónìí, àní láti ìsinsìnyìí lọ.

15. OLUWA yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà, wọn óo sì máa gbọ̀n bí ewé ojú omi. OLUWA yóo fà wọ́n tu kúrò ninu ilẹ̀ dáradára tí ó fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì fọ́n wọn káàkiri òdìkejì odò Yufurate, nítorí ère oriṣa Aṣerimu tí wọ́n ṣe tí ó mú OLUWA bínú.

16. Yóo kọ Israẹli sílẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Jeroboamu dá ati èyí tí ó mú kí Israẹli dá pẹlu.”

17. Aya Jeroboamu bá gbéra, ó pada sí Tirisa. Bí ó ti fẹ́ wọlé ni ọmọ tí ń ṣàìsàn náà kú.

18. Àwọn ọmọ Israẹli sin ín, wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ bí ọ̀rọ̀ tí OLUWA gba ẹnu wolii Ahija, iranṣẹ rẹ̀ sọ.

19. Gbogbo àwọn nǹkan yòókù tí Jeroboamu ọba ṣe: àwọn ogun tí ó jà, ati bí ó ti ṣe ṣe ìjọba rẹ̀, gbogbo rẹ̀ wà ninu ìwé àkọsílẹ̀ Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

20. Jeroboamu jọba fún ọdún mejilelogun. Lẹ́yìn náà, ó kú, wọ́n sì sin ín. Nadabu, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

21. Ẹni ọdún mọkanlelogoji ni Rehoboamu ọmọ Solomoni nígbà tí ó gun orí oyè ní ilẹ̀ Juda, ọdún mẹtadinlogun ni ó fi jọba ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin gbogbo ilẹ̀ Israẹli fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ̀. Naama ará Amoni ni ìyá rẹ̀.

22. Àwọn ẹ̀yà Juda ṣẹ̀ sí OLUWA, wọ́n sì ṣe ohun tí ó mú un bínú lọpọlọpọ ju gbogbo àwọn baba ńlá wọn lọ.

23. Nítorí wọ́n kọ́ pẹpẹ ìrúbọ, wọ́n sì ri ọ̀wọ̀n òkúta ati ère oriṣa Aṣerimu mọ́lẹ̀ lórí gbogbo òkè ati lábẹ́ igi tútù káàkiri.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 14