Ẹni ọdún mọkanlelogoji ni Rehoboamu ọmọ Solomoni nígbà tí ó gun orí oyè ní ilẹ̀ Juda, ọdún mẹtadinlogun ni ó fi jọba ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin gbogbo ilẹ̀ Israẹli fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ̀. Naama ará Amoni ni ìyá rẹ̀.