Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 1:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò yìí, Dafidi ọba ti di arúgbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aṣọ tí ó nípọn ni wọ́n fi ń bò ó, òtútù a tún máa mú un.

2. Nítorí náà, àwọn iranṣẹ rẹ̀ wí fún un pé, “Kabiyesi, jẹ́ kí á wá ọdọmọbinrin kan fún ọ, tí yóo máa wà pẹlu rẹ, tí yóo sì máa tọ́jú rẹ. Yóo máa sùn tì ọ́ kí ara rẹ lè máa móoru.”

3. Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá ọdọmọbinrin tí ó lẹ́wà gidigidi ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli. Wọ́n rí ọdọmọbinrin arẹwà kan ní ìlú Ṣunemu, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abiṣagi, wọ́n sì mú un tọ Dafidi wá.

4. Ọdọmọbinrin náà dára gan-an; ó wà lọ́dọ̀ ọba, ó ń tọ́jú rẹ̀, ṣugbọn ọba kò bá a lòpọ̀ rárá.

5. Adonija, ọmọ tí Hagiti bí fún Dafidi, bẹ̀rẹ̀ sí gbéraga, ó ń wí pé, “Èmi ni n óo jọba.” Ó bá lọ tọ́jú kẹ̀kẹ́ ogun, ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati aadọta ọkunrin tí yóo máa sáré níwájú rẹ̀.

6. Adonija yìí ni wọ́n bí tẹ̀lé Absalomu, ó jẹ́ arẹwà ọkunrin; baba rẹ̀ kò sì fi ìgbà kan dojú kọ ọ́ kí ó bá a wí nítorí ohunkohun rí.

7. Adonija lọ jíròrò pẹlu Joabu, ọmọ Seruaya, ati Abiatari alufaa, àwọn mejeeji tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́.

8. Ṣugbọn Sadoku alufaa, ati Bẹnaya ọmọ Jehoiada, ati Natani wolii, ati Ṣimei, Rei, ati àwọn akọni Dafidi kò faramọ́ ohun tí Adonija ṣe, wọn kò sì sí lẹ́yìn rẹ̀.

9. Ní ọjọ́ kan, Adonija fi ọpọlọpọ aguntan, pẹlu akọ mààlúù, ati àbọ́pa mààlúù rúbọ níbi Àpáta Ejò, lẹ́bàá orísun Enrogeli, ó sì pe àwọn ọmọ ọba yòókù, àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba ní ilẹ̀ Juda.

10. Ṣugbọn kò pe Natani wolii, tabi Bẹnaya, tabi àwọn akọni ninu àwọn jagunjagun ọba, tabi Solomoni, arakunrin rẹ̀.

11. Natani bá tọ Batiṣeba ìyá Solomoni lọ, ó bi í pé, “Ṣé o ti gbọ́ pé Adonija ọmọ Hagiti ti fi ara rẹ̀ jọba, Dafidi ọba kò sì mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 1