Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 7:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Eliṣa dáhùn pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ní àkókò yìí lọ́la, ní ẹnubodè Samaria, àwọn eniyan yóo ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan, tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kan.”

2. Ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun tí wọ́n wà níbẹ̀, tí ó jẹ́ aṣojú ọba dá Eliṣa lóhùn, ó ní, “Bí OLUWA bá tilẹ̀ da àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá, ǹjẹ́ ohun tí o sọ yìí lè rí bẹ́ẹ̀?”Eliṣa dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.”

3. Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin kan wà ní ẹnubodè Samaria, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Kí ló dé tí a óo fi dúró síbí títí tí a óo fi kú?

4. Bí a bá lọ sinu ìlú ebi yóo pa wá kú nítorí ìyàn wà níbẹ̀, bí a bá sì dúró níbí, a óo kú bákan náà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria. Bí wọ́n bá pa wá, a jẹ́ pé ikú yá, bí wọ́n bá sì dá wa sí, a óo wà láàyè.”

5. Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pofírí, wọ́n lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọn kò rí ẹnìkan kan.

6. OLUWA ti mú kí àwọn ọmọ ogun Siria gbọ́ ìró ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin ati ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Wọ́n wí fún ara wọn pé ọba Israẹli ti lọ bẹ àwọn ọmọ ogun Hiti ati ti Ijipti láti wá bá àwọn jà.

7. Nítorí náà, wọ́n sá lọ ní àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n fi ibùdó ogun wọn ati àwọn ẹṣin wọn ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.

8. Nígbà tí àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin náà dé ìkangun ibùdó ogun, wọ́n wọ inú àgọ́ kan lọ. Wọ́n jẹ ohun tí wọ́n bá níbẹ̀; wọ́n sì mu. Wọ́n kó fadaka ati wúrà ati aṣọ tí wọ́n rí níbẹ̀, wọ́n lọ kó wọn pamọ́. Wọ́n pada wá, wọ́n wọ inú àgọ́ mìíràn, wọ́n tún ṣe bákan náà.

9. Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ohun tí à ń ṣe yìí kò dára, ọjọ́ ìròyìn ayọ̀ ni ọjọ́ òní. Bí a bá dákẹ́, tí a sì dúró di òwúrọ̀ a óo jìyà. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ fún àwọn ará ilé ọba.”

10. Wọ́n bá lọ sí Samaria, wọ́n sì kígbe pe àwọn aṣọ́nà láti ẹnubodè pé, “A ti lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, a kò rí ẹnìkan kan níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbúròó ẹnìkan kan. Àwọn ẹṣin ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn wà bí wọ́n ṣe so wọ́n mọ́lẹ̀, gbogbo àwọn àgọ́ wọn sì wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Siria ti fi wọ́n sílẹ̀.”

11. Àwọn aṣọ́nà bá sọ fún àwọn tí wọ́n wà ní ààfin ọba.

12. Ọba dìde ní òru ọjọ́ náà, ó sọ fún àwọn olórí ogun rẹ̀ pé, “Mo mọ ète àwọn ará Siria. Wọ́n mọ̀ pé ìyàn mú ninu ìlú wa, nítorí náà ni wọ́n ṣe fi ibùdó ogun wọn sílẹ̀ láti sá pamọ́ sinu igbó, pẹlu èrò pé a óo wá oúnjẹ wá. Kí wọ́n lè mú wa láàyè, kí wọ́n sì gba ìlú wa.”

13. Ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun náà dá ọba lóhùn pé, “Ṣebí àwọn eniyan náà yóo kú ni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n ti kú. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á rán àwọn ọkunrin kan pẹlu ẹṣin marun-un tí ó kù láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 7