Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 5:8-16 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Nígbà tí Eliṣa gbọ́ pé ọba Israẹli ti fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ranṣẹ sí i pé, “Kí ló dé tí o fi fa aṣọ rẹ ya? Mú ọkunrin náà wá sọ́dọ̀ mi, kí ó lè mọ̀ pé wolii kan wà ní Israẹli.”

9. Naamani bá lọ ti òun ti àwọn ẹṣin ati kẹ̀kẹ́-ogun rẹ̀, ó sì dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé Eliṣa.

10. Eliṣa rán iranṣẹ kan kí ó sọ fún un pé kí ó lọ wẹ ara rẹ̀ ninu odò Jọdani ní ìgbà meje, yóo sì rí ìwòsàn.

11. Ṣugbọn Naamani fi ibinu kúrò níbẹ̀, ó ní, “Mo rò pé yóo jáde wá, yóo gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀, yóo fi ọwọ́ rẹ̀ pa ibẹ̀, yóo sì ṣe àwòtán ẹ̀tẹ̀ náà ni.

12. Ṣé àwọn odò Abana ati odò Faripari tí wọ́n wà ní Damasku kò dára ju gbogbo àwọn odò tí wọ́n wà ní Israẹli lọ ni? Ṣebí mo lè wẹ̀ ninu wọn kí n sì mọ́!” Ó bá yipada, ó ń bínú lọ.

13. Àwọn iranṣẹ rẹ̀ bá gbà á níyànjú pé, “Baba, ṣé bí wolii náà bá sọ pé kí o ṣe ohun tí ó le ju èyí lọ, ṣé o kò ní ṣe é? Kí ló dé tí o kò lè wẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, kí o sì rí ìwòsàn gbà?”

14. Naamani bá lọ sí odò Jọdani, ó wẹ̀ ní ìgbà meje gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti pàṣẹ fún un, ó rí ìwòsàn, ara rẹ̀ sì jọ̀lọ̀ bí ara ọmọde.

15. Lẹ́yìn náà ó pada pẹlu àwọn iranṣẹ rẹ̀ sọ́dọ̀ Eliṣa, ó ní, “Nisinsinyii ni mo mọ̀ pé kò sí ọlọrun mìíràn ní gbogbo ayé àfi Ọlọrun Israẹli. Nítorí náà jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn yìí lọ́wọ́ iranṣẹ rẹ.”

16. Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Mo fi OLUWA tí mò ń sìn búra pé n kò ní gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ.”Naamani rọ̀ ọ́ kí ó gbà wọ́n, ṣugbọn ó kọ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 5