Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 5:16-27 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ṣugbọn Eliṣa dáhùn pé, “Mo fi OLUWA tí mò ń sìn búra pé n kò ní gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ.”Naamani rọ̀ ọ́ kí ó gbà wọ́n, ṣugbọn ó kọ̀.

17. Naamani bá ní, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè láti bu erùpẹ̀ ẹrù kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ meji lọ sílé nítorí láti òní lọ, iranṣẹ rẹ kì yóo rúbọ sí ọlọrun mìíràn bíkòṣe OLUWA.

18. Mo bẹ̀bẹ̀ kí OLUWA dáríjì mí nígbà tí mo bá tẹ̀lé oluwa mi lọ sinu tẹmpili Rimoni, oriṣa Siria láti rúbọ sí i. Bí oluwa mi bá gbé ara lé apá mi, tí èmi náà sì tẹríba ninu tẹmpili Rimoni, kí OLUWA dáríjì iranṣẹ rẹ.”

19. Eliṣa sọ fún un pé “Máa lọ ní alaafia.” Naamani bá lọ.Ṣugbọn kò tíì rìn jìnnà,

20. nígbà tí Gehasi, iranṣẹ Eliṣa, sọ ninu ara rẹ̀ pé, “Olúwa mi jẹ́ kí Naamani ará Siria yìí lọ láì gba ohun tí ó mú wá lọ́wọ́ rẹ̀. Mo fi OLUWA búra pé, n óo sáré tẹ̀lé e láti gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀.”

21. Ó bá sáré tẹ̀lé Naamani. Nígbà tí Naamani rí i pé ẹnìkan ń sáré bọ̀, ó sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun tí ó gùn láti pàdé rẹ̀, ó bèèrè pé, “Ṣé kò sí nǹkan?”

22. Gehasi dáhùn pé, “Rárá, kò sí nǹkan. Oluwa mi ni ó rán mi sí ọ pé, ‘Nisinsinyii ni meji ninu àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọn ń gbé òkè Efuraimu wá sọ́dọ̀ mi. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ìwọ̀n talẹnti fadaka kan ati aṣọ meji.’ ”

23. Naamani sì rọ̀ ọ́ kí ó gba ìwọ̀n talẹnti meji. Ó di owó náà sinu àpò meji pẹlu aṣọ meji. Ó pàṣẹ fún iranṣẹ meji kí wọ́n bá Gehasi gbé wọn lọ.

24. Nígbà tí wọ́n dé orí òkè tí Eliṣa ń gbé, Gehasi gba àwọn ẹrù náà lórí wọn, ó gbé wọn sinu ilé, ó sì dá àwọn iranṣẹ Naamani pada.

25. Nígbà tí ó wọlé, Eliṣa bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Níbo ni o lọ?”Ó dáhùn pé, “N kò lọ sí ibìkan kan.”

26. Eliṣa dáhùn pé, “Ṣé o kò mọ̀ pé mo wà pẹlu rẹ ninu ẹ̀mí, nígbà tí Naamani sọ̀kalẹ̀ ninu kẹ̀kẹ́-ogun, tí ó gùn, tí ó wá láti pàdé rẹ? Ṣé àkókò yìí ni ó yẹ láti gba fadaka tabi aṣọ tabi olifi tabi ọgbà àjàrà tabi aguntan tabi mààlúù tabi iranṣẹkunrin tabi iranṣẹbinrin?

27. Nítorí ìdí èyí, ẹ̀tẹ̀ Naamani yóo lẹ̀ mọ́ ọ lára ati ìdílé rẹ ati ìrandíran rẹ títí lae.”Gehasi sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Eliṣa ní adẹ́tẹ̀, ó funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 5