Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 3:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún kejidinlogun tí Jehoṣafati jọba ní Juda, Joramu, ọmọ Ahabu, jọba lórí Israẹli ní Samaria. Ó sì wà lórí oyè fún ọdún mejila.

2. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA, ṣugbọn ó wó òpó oriṣa Baali tí Baba rẹ̀ mọ, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì pọ̀ tó ti baba rẹ̀ tabi ti Jesebẹli ìyá rẹ̀.

3. Ó mú kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀ lọpọlọpọ gẹ́gẹ́ bíi Jeroboamu, tí ó ti jọba ṣáájú kò sì ronupiwada.

4. Meṣa, ọba Moabu, a máa sin aguntan; ní ọdọọdún, a máa fún ọba Israẹli ní ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọ̀dọ́ aguntan ati irun ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) àgbò, gẹ́gẹ́ bí ìṣákọ́lẹ̀.

5. Ṣugbọn lẹ́yìn tí Ahabu kú, ọba Moabu ṣọ̀tẹ̀, kò san ìṣákọ́lẹ̀ náà fún ọba Israẹli mọ́.

6. Joramu ọba bá gbéra ní Samaria, ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ.

7. Ó ranṣẹ sí Jehoṣafati ọba Juda pé, “Ọba Moabu ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ṣé o óo bá mi lọ láti bá a jagun?”Jehoṣafati dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ, ìwọ ni o ni mí, ìwọ ni o sì ni àwọn ọmọ ogun mi ati àwọn ẹṣin mi pẹlu.”

8. Jehoṣafati bèèrè pé, “Ọ̀nà wo ni a óo gbà lọ?”Joramu sì dáhùn pé, “Ọ̀nà aṣálẹ̀ Edomu ni.”

9. Ni Joramu, ati ọba Juda ati ọba Edomu bá gbéra láti lọ sójú ogun. Lẹ́yìn tí wọ́n ti rìn fún ọjọ́ meje, kò sí omi mímu mọ́ fún wọn ati fún àwọn ẹranko tí wọ́n ru ẹrù wọn.

10. Joramu ọba ní, “Ó mà ṣe o, OLUWA pe àwa ọba mẹtẹẹta jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.”

11. Ó bá bèèrè pé, “Ṣé kò sí wolii OLUWA kan níhìn-ín tí ó lè bá wa wádìí lọ́wọ́ OLUWA?”Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Joramu bá dáhùn pé, “Eliṣa ọmọ Ṣafati, tí ó jẹ́ iranṣẹ Elija, wà níhìn-ín.”

12. Jehoṣafati dáhùn pé, “Wolii òtítọ́ ni.” Àwọn ọba mẹtẹẹta náà bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

13. Eliṣa sọ fún Joramu ọba pé, “Lọ sọ́dọ̀ àwọn wolii baba ati ìyá rẹ. Àbí, kí ló pa èmi ati ìwọ pọ̀?”Joramu dáhùn pé, “Rárá, OLUWA ni ó ti pe àwa ọba mẹtẹẹta yìí jọ láti fi wá lé ọba Moabu lọ́wọ́.”

14. Eliṣa bá dáhùn pé, “Bí OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí mò ń sìn ṣe wà láàyè, n kì bá tí dá ọ lóhùn bí kò bá sí ti Jehoṣafati, ọba Juda, tí ó bá ọ wá.”

15. Ó ní, “Ẹ pe akọrin kan wá.”Bí akọrin náà ti ń kọrin ni agbára OLUWA bà lé Eliṣa,

16. ó bá ní, “OLUWA ní òun óo sọ àwọn odò gbígbẹ wọnyi di adágún omi.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 3