Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 22:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọmọ ọdún mẹjọ ni Josaya nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanlelọgbọn. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Jedida ọmọ Adaya ará Bosikati.

2. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ó tẹ̀ sí ọ̀nà Dafidi, baba ńlá rẹ̀, kò sì ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí àpẹẹrẹ tí Dafidi fi lélẹ̀.

3. Ní ọdún kejidinlogun tí Josaya jọba, ó rán Ṣafani, akọ̀wé rẹ̀, ọmọ Asalaya, ọmọ Meṣulamu, sí ilé OLUWA pé kí ó

4. lọ sí ọ̀dọ̀ Hilikaya olórí alufaa, kí ó ṣírò iye owó tí àwọn alufaa tí wọ́n wà lẹ́nu ọ̀nà ti gbà lọ́wọ́ àwọn eniyan,

5. kí ó gbé owó náà fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA. Àwọn ni wọn yóo máa san owó fún

6. àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àwọn ọ̀mọ̀lé ati àwọn agbẹ́kùúta, kí wọ́n sì ra igi ati òkúta tí wọn yóo lò fún àtúnṣe ilé OLUWA.

7. Ó ní àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé náà kò ní nílò láti ṣe ìṣirò owó tí wọn ń ná, nítorí pé gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́ olóòótọ́.

8. Ṣafani jíṣẹ́ ọba fún Hilikaya; Hilikaya olórí alufaa, sì sọ fún un pé òun ti rí ìwé òfin ninu ilé OLUWA. Ó fún Ṣafani ní ìwé náà, ó sì kà á.

9. Ṣafani bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba, ó sọ fún ọba pé, àwọn iranṣẹ rẹ̀ ti kó owó tí ó wà ninu ilé OLUWA fún àwọn tí wọ́n ń ṣe àkóso àtúnṣe ilé OLUWA,

10. ati pé Hilikaya fún òun ní ìwé kan; ó sì kà á sí etígbọ̀ọ́ ọba.

11. Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ inú ìwé náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 22