Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 18:26-37 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Nígbà náà ni Eliakimu, ọmọ Hilikaya ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, bá àwa iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki nítorí pé a gbọ́. Má sọ èdè Heberu mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n wà lórí odi ń gbọ́ ohun tí ò ń sọ.”

27. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ rò pé ẹ̀yin ati ọba nìkan ni ọba Asiria rán mi sí ni? Rárá, àwọn tí wọ́n wà lórí odi náà wà lára àwọn tí mò ń bá sọ̀rọ̀. Àwọn náà yóo jẹ ìgbẹ́ ara wọn tí wọn yóo sì mu ìtọ̀ ara wọn bí ẹ̀yin náà.”

28. Nígbà náà ni Rabuṣake kígbe sókè rara ní èdè Heberu tíí ṣe èdè àwọn ará Juda ó ní, “Ẹ gbọ́ ohun tí ọba Asiria ń sọ fun yín;

29. ó ní òun ń kìlọ̀ fun yín pé kí ẹ má jẹ́ kí Hesekaya tàn yín jẹ, kò lè gbà yín sílẹ̀.

30. Ó ní kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ó mú ki ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA kí ó máa sọ pé OLUWA yóo gbà yín sílẹ̀, ati pé kò ní jẹ́ kí ogun Asiria kó ìlú yín.

31. Ẹ má ṣe gbọ́ ti Hesekaya; nítorí pé ọba Asiria ní kí ẹ jáde wá kí ẹ bá òun ṣe àdéhùn alaafia; òun yóo gbà yín láàyè láti máa jẹ èso àjàrà ninu ọgbà àjàrà yín. Ẹ óo máa jẹ èso orí igi ọ̀pọ̀tọ́ yín, ẹ óo sì máa mu omi láti inú kànga yín;

32. títí di ìgbà tí òun óo fi ko yín lọ sí ilẹ̀ mìíràn tí yóo dàbí tiyín, ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati waini, ilẹ̀ tí ó kún fún oúnjẹ ati ọgbà àjàrà, ilẹ̀ tí ó kún fún igi olifi ati oyin, kí ẹ lè wà láàyè, kí ẹ má baà kú. Ẹ má jẹ́ kí Hesekaya tàn yín, kí ẹ máa rò pé OLUWA yóo gbà yín.

33. Ṣé ọlọrun àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn gbà wọ́n lọ́wọ́ ọba Asiria?

34. Níbo ni ọlọrun Hamati ati ti Aripadi wà? Níbo ni àwọn ọlọrun Sefafaimu, ati ti Hena ati ti Ifa wà? Ṣé wọ́n gba Samaria lọ́wọ́ mi?

35. Nígbà wo ni ọ̀kan ninu àwọn ọlọrun orílẹ̀-èdè wọnyi gba orílẹ̀-èdè wọn lọ́wọ́ ọba Asiria rí, tí OLUWA yóo fi gba Jerusalẹmu lọ́wọ́ mi?”

36. Àwọn eniyan náà dákẹ́ jẹ́ẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Hesekaya ti pàṣẹ fún wọn, wọn kò sọ ọ̀rọ̀ kankan.

37. Nígbà náà ni Eliakimu, tí ń ṣe àkóso ààfin ati Ṣebina, akọ̀wé ọba, ati Joa, tí ń ṣe àkóso ìwé ìrántí fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, wọ́n sì lọ sọ ohun tí olórí ogun náà wí fun ọba.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 18