Nígbà náà ni Eliakimu, tí ń ṣe àkóso ààfin ati Ṣebina, akọ̀wé ọba, ati Joa, tí ń ṣe àkóso ìwé ìrántí fa aṣọ wọn ya láti fi ìbànújẹ́ wọn hàn, wọ́n sì lọ sọ ohun tí olórí ogun náà wí fun ọba.