Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 15:10-22 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ṣalumu ọmọ Jabeṣi dìtẹ̀ mọ́ ọn, ó pa á ní Ibileamu, ó sì jọba dípò rẹ̀.

11. Gbogbo nǹkan yòókù tí Sakaraya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

12. OLUWA ṣèlérí fún Jehu pé, “Àwọn ọmọ rẹ títí dé ìran kẹrin yóo jọba ní Israẹli.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

13. Ní ọdún kọkandinlogoji tí Asaraya ti jọba ní Juda ni Ṣalumu, ọmọ Jabeṣi, jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó wà lórí oyè fún oṣù kan.

14. Menahemu ọmọ Gadi lọ sí Samaria láti Tirisa, ó pa Ṣalumu ọba, ó sì jọba dípò rẹ̀.

15. Gbogbo nǹkan yòókù tí Ṣalumu ṣe, ati ìwà ọ̀tẹ̀ tí ó hù ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

16. Ní àkókò náà Menahemu pa ìlú Tapua run, ati àwọn ìlú tí wọ́n yí i ká láti Tirisa, nítorí pé wọn kò ṣí ìlẹ̀kùn ìlú náà fún un, ó sì la inú gbogbo àwọn aboyún tí wọ́n wà níbẹ̀.

17. Ní ọdún kọkandinlogoji tí Asaraya jọba ní Juda, ni Menahemu, ọmọ Gadi, jọba lórí Israẹli ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mẹ́wàá.

18. Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, nítorí pé ó tẹ̀lé ọ̀nà Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.

19. Pulu, tí à ń pè ní Tigilati Pileseri, ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ Israẹli; kí ó baà lè ran Menahemu lọ́wọ́ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, Menahemu fún un ní ẹgbẹrun (1,000) talẹnti owó fadaka.

20. Ọwọ́ àwọn ọlọ́rọ̀ Israẹli ni ọba ti gba owó náà, ó pàṣẹ pé kí olukuluku dá aadọta ṣekeli owó fadaka. Ọba Asiria bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.

21. Gbogbo nǹkan yòókù tí Menahemu ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

22. Ó kú, wọ́n sì sin òkú rẹ̀, Pekahaya, ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 15