Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 14:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún keji tí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi jọba ní Israẹli ni Amasaya ọmọ Joaṣi jọba ní Juda.

2. Ẹni ọdún mẹẹdọgbọn ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún mọkandinlọgbọn ní Jerusalẹmu. Jehoadini, ará Jerusalẹmu, ni ìyá rẹ̀.

3. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA, ṣugbọn kò dàbí ti Dafidi baba ńlá rẹ̀; ohun gbogbo tí Joaṣi baba rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe.

4. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ oriṣa run; àwọn eniyan ṣì ń rú ẹbọ níbẹ̀, wọ́n sì ń sun turari.

5. Nígbà tí ìjọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀ tán, ó pa àwọn olórí ogun tí wọ́n pa baba rẹ̀.

6. Ṣugbọn kò pa àwọn ọmọ wọn nítorí pé òfin Mose pa á láṣẹ pé, “A kò gbọdọ̀ pa baba nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọdọ̀ pa ọmọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ baba. Olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”

7. Amasaya pa ẹgbaarun (10,000) ninu àwọn ọmọ ogun Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀. Ó ṣẹgun Sela, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jokiteeli, orúkọ yìí ni ìlú náà ń jẹ́ títí di òní yìí.

8. Lẹ́yìn náà, Amasaya ranṣẹ sí Jehoaṣi, ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu, ọba Israẹli, láti pè é níjà sí ogun.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 14