Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 11:5-19 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ìdámẹ́ta yín tí ó bá wá sí ibi iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi yóo máa ṣọ́ ààfin.

6. (Ìdámẹ́ta yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà Suri; ìdámẹ́ta yòókù yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà tí ó wà lẹ́yìn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin), wọn yóo dáàbò bo ààfin.

7. Àwọn ìpín mejeeji tí wọ́n bá ṣíwọ́ iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi, yóo wá dúró ní ilé OLUWA láti dáàbò bo ọba.

8. Wọn yóo dáàbò bo ọba pẹlu idà ní ọwọ́ wọn, wọn yóo sì máa bá a lọ sí ibikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.”

9. Àwọn olórí ogun náà gbọ́ àṣẹ tí Jehoiada, alufaa, pa fún wọn, wọ́n sì kó àwọn ọmọ ogun wọn, tí wọ́n ṣíwọ́ iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ati àwọn tí wọn yóo wọ iṣẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.

10. Jehoiada bá fún àwọn olórí ogun náà ní àwọn ọ̀kọ̀ ati apata Dafidi, tí wọ́n kó pamọ́ sinu ilé OLUWA.

11. Àwọn ọmọ ogun sì dúró pẹlu ohun ìjà lọ́wọ́ wọn láti ìhà gúsù ilé náà títí dé ìhà àríwá rẹ̀, wọ́n yí pẹpẹ ati ilé náà ká.

12. Lẹ́yìn náà ni ó mú Joaṣi, ọmọ ọba jáde síta, ó fi adé ọba dé e lórí, ó sì fún un ní ìwé òfin. Lẹ́yìn náà ni ó da òróró sí i lórí láti fi jọba. Àwọn eniyan pàtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe pé, “Kabiyesi, kí ẹ̀mí ọba ó gùn!”

13. Nígbà tí Atalaya gbọ́ ariwo àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ati ti àwọn eniyan, ó jáde lọ sí ilé OLUWA níbi tí àwọn eniyan péjọ sí.

14. Nígbà tí ó wo ọ̀kánkán, ó wò, ó rí ọba náà tí ó dúró ní ẹ̀bá òpó, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA gẹ́gẹ́ bí àṣà, ó sì rí i tí àwọn olórí ogun ati àwọn afunfèrè yí i ká, tí àwọn eniyan sì ń fi ayọ̀ pariwo, tí wọ́n sì ń fọn fèrè. Atalaya fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn, ó sì kígbe pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!”

15. Jehoiada kò fẹ́ kí wọ́n pa Atalaya ninu ilé OLUWA, nítorí náà ó pàṣẹ fún àwọn olórí ogun, ó ní, “Ẹ mú un jáde, kí ó wà ní ààrin yín bí ẹ ti ń mú un lọ; ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gbà á là, pípa ni kí ẹ pa á.”

16. Wọ́n bá mú un gba ẹnu ọ̀nà tí àwọn ẹṣin máa ń gbà wọ ààfin, wọ́n sì pa á.

17. Jehoiada alufaa mú kí Joaṣi ọba ati àwọn eniyan dá majẹmu pẹlu OLUWA pé àwọn yóo jẹ́ tirẹ̀; ó sì tún mú kí àwọn eniyan náà bá ọba dá majẹmu.

18. Lẹ́yìn náà, àwọn eniyan lọ sí ilé oriṣa Baali, wọ́n wó o, wọ́n sì wó àwọn pẹpẹ rẹ̀ ati àwọn ère rẹ̀ lulẹ̀. Wọ́n pa Matani, alufaa Baali, níwájú àwọn pẹpẹ náà.Jehoiada sì fi àwọn olùṣọ́ tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ sí ìtọ́jú ilé OLUWA.

19. Òun ati àwọn olórí ogun ati àwọn tí wọ́n ń ṣọ́ ọba ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin sin ọba láti ilé OLUWA lọ sí ààfin. Ọba gba ẹnu ọ̀nà àwọn olùṣọ́ wọlé, ó sì jókòó lórí ìtẹ́.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 11