Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 10:10-22 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Èyí fihàn dájú pé gbogbo ohun tí OLUWA sọ nípa ìdílé Ahabu yóo ṣẹ. OLUWA ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí láti ẹnu Elija, wolii rẹ̀.”

11. Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu tí wọn ń gbé Jesireeli ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ati àwọn alufaa; kò dá ọ̀kan ninu wọn sí.

12. Jehu kúrò ní Jesireeli, ó ń lọ sí Samaria. Nígbà tí ó dé ibìkan tí wọ́n ń pè ní Bẹtekedi, níbi tí àwọn olùṣọ́ aguntan ti máa ń rẹ́ irun aguntan,

13. ó pàdé àwọn ìbátan Ahasaya, ọba Juda, ó bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni yín?”Wọ́n dáhùn pé, “Ìbátan Ahasaya ni wá. Jesireeli ni à ń lọ láti lọ kí àwọn ọmọ ọba ati àwọn ìdílé ọba.”

14. Jehu pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mú wọn láàyè. Wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ibi kòtò tí ó wà ní Bẹtekedi. Gbogbo wọn jẹ́ mejilelogoji, kò sì dá ọ̀kankan ninu wọn sí.

15. Jehu tún ń lọ, ó pàdé Jehonadabu, ọmọ Rekabu, tí ń bọ̀ wá pàdé rẹ̀. Lẹ́yìn tí Jehu kí i tán, ó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ọkàn rẹ mọ́ sí mi bí ọkàn mi ti mọ́ sí ọ?”Jehonadabu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”Jehu dáhùn, ó ní, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.” Ó bá na ọwọ́ sí Jehu, Jehu sì fà á sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀.

16. Ó ní, “Tẹ̀lé mi, kí o wá wo ìtara mi fún OLUWA.” Wọ́n sì jọ gun kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ lọ sí Samaria.

17. Nígbà tí wọ́n dé Samaria, Jehu pa gbogbo àwọn ìbátan Ahabu, kò sì fi ọ̀kankan ninu wọn sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ láti ẹnu Elija.

18. Lẹ́yìn náà, Jehu pe gbogbo àwọn ará Samaria jọ, ó sọ fún wọn pé, “Ahabu sin oriṣa Baali díẹ̀, ṣugbọn n óo sìn ín lọpọlọpọ.

19. Nítorí náà, ẹ pe gbogbo àwọn wolii Baali ati àwọn tí ń bọ ọ́ ati àwọn alufaa rẹ̀ wá fún mi. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe aláìwá nítorí mo fẹ́ ṣe ìrúbọ ńlá sí Baali. Ẹnikẹ́ni tí kò bá wá, pípa ni a óo pa á.” Ṣugbọn Jehu ń ṣe èyí láti rí ààyè pa gbogbo àwọn olùsìn Baali run ni.

20. Ó pàṣẹ pé, “Ẹ ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ìsìn Baali,” wọ́n sì kéde rẹ̀.

21. Jehu ranṣẹ sí àwọn ẹlẹ́sìn Baali ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli; kò sí ẹnìkan ninu wọn tí kò wá. Gbogbo wọn lọ sinu ilé ìsìn Baali, wọ́n sì kún inú rẹ̀ títí dé ẹnu ọ̀nà kan sí ekeji.

22. Jehu sì pàṣẹ fún ẹni tí ń tọ́jú ibi tí wọn ń kó aṣọ ìsìn pamọ́ sí pé kí ó kó wọn jáde fún àwọn tí ń bọ Baali.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 10