Jehu ranṣẹ sí àwọn ẹlẹ́sìn Baali ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli; kò sí ẹnìkan ninu wọn tí kò wá. Gbogbo wọn lọ sinu ilé ìsìn Baali, wọ́n sì kún inú rẹ̀ títí dé ẹnu ọ̀nà kan sí ekeji.