Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 9:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Abimeleki ọmọ Gideoni lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan ìyá rẹ̀ ní Ṣekemu, ó bá àwọn ati gbogbo ìdílé wọn sọ̀rọ̀, ó ní,

2. kí wọn bèèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu pé, èwo ni wọ́n fẹ́, tí wọ́n sì rò pé ó dára jù fún wọn, kí gbogbo aadọrin ọmọ Gideoni máa jọba lé wọn lórí ni, tabi kí ẹnìkan ṣoṣo jọba lórí wọn? Ó rán wọn létí pé, ìyekan wọn ni òun jẹ́.

3. Àwọn eniyan ìyá rẹ̀ bá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní etígbọ̀ọ́ gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu, wọn sì gbà láti tẹ̀lé Abimeleki tayọ̀tayọ̀. Wọ́n ní, “Arakunrin wa ni Abimeleki jẹ́.”

4. Wọ́n mú aadọrin owó fadaka ninu ilé oriṣa Baali-beriti fún Abimeleki. Ó fi owó yìí kó àwọn oníjàgídíjàgan ati ìpátá kan jọ wọ́n sì ń tẹ̀lé e kiri.

5. Ó bá lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Ofira, ó pa gbogbo aadọrin àwọn arakunrin rẹ̀ lórí òkúta kan, àfi Jotamu àbíkẹ́yìn Gideoni nìkan ni ó ṣẹ́kù, nítorí pé òun sá pamọ́.

6. Gbogbo àwọn ará ìlú Ṣekemu ati ti Bẹtimilo bá para pọ̀, wọ́n fi Abimeleki jọba níbi igi Oaku kan tí ó wà níbi ọ̀wọ̀n tí ó wà ní Ṣekemu.

7. Nígbà tí Jotamu gbọ́, ó gun orí òkè Gerisimu lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ọkunrin Ṣekemu, kí Ọlọrun lè gbọ́ tiyín.

8. Ní àkókò kan, àwọn igi oko kó ara wọn jọ pé wọ́n fẹ́ ọba, wọ́n lọ sọ́dọ̀ igi Olifi, wọ́n wí fún un pé kí ó máa jọba lórí wọn.

9. Ṣugbọn igi Olifi dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí n pa òróró ṣíṣe tì, tí àwọn oriṣa ati àwọn eniyan fi ń dá ara wọn lọ́lá tì, kí n má ṣe é mọ́, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’

10. Àwọn igi bá lọ sí ọ̀dọ̀ igi ọ̀pọ̀tọ́, wọ́n sọ fún un pé kí ó wá jọba lórí àwọn.

11. Ṣugbọn igi ọ̀pọ̀tọ́ dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí n pa èso mi dáradára tí ó ládùn tì, kí n wá jọba lórí yín?’

12. Àwọn igi bá tún lọ sọ́dọ̀ igi àjàrà, wọ́n wí fún un pé kí ó wá jọba lórí àwọn.

13. Ṣugbọn igi àjàrà dá wọn lóhùn pé, ‘Ṣé kí ń pa ọtí mi, tí ń mú inú àwọn oriṣa ati àwọn eniyan dùn tì, kí n wá jọba lórí ẹ̀yin igi?’

14. Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn igi sọ fún igi ẹ̀gún pé kí ó wá jọba lórí àwọn.

15. Igi ẹ̀gún bá dá àwọn igi lóhùn pé, ‘Tí ó bá jẹ́ pé tinútinú yín ni ẹ fi fẹ́ kí n jọba yín, ẹ wá sábẹ́ ìbòòji mi, n óo sì dáàbò bò yín. Ṣugbọn bí bẹ́ẹ̀ bá kọ́, iná yóo yọ jáde láti ara ẹ̀gún mi, yóo sì jó igi kedari tí ó wà ní Lẹbanoni run.’

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 9