Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 8:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ará Efuraimu bèèrè lọ́wọ́ Gideoni pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, tí o kò pè wá, nígbà tí o lọ gbógun ti àwọn ara Midiani?” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí i pẹlu ibinu.

2. Ó dá wọn lóhùn, ó ní, “Kí ni mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe? Ohun tí ẹ̀yin ará Efuraimu ṣe, tí ẹ rò pé ohun kékeré ni yìí, ó ju gbogbo ohun tí àwọn ará Abieseri ṣe, tí ẹ kà kún nǹkan bàbàrà lọ.

3. Ẹ̀yin ni Ọlọrun fi Orebu ati Seebu, àwọn ọmọ ọba Midiani mejeeji lé lọ́wọ́. Kí ni ohun tí mo ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tí ẹ̀yin ṣe?” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bí ó ṣe dá wọn lóhùn, inú wọ́n yọ́.

4. Gideoni bá lọ sí odò Jọdani, ó sì kọjá odò náà sí òdìkejì rẹ̀, òun ati àwọn ọọdunrun (300) ọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé e. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, sibẹsibẹ wọ́n ń lé àwọn ará Midiani lọ.

5. Ó bẹ àwọn ará Sukotu, ó ní, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún àwọn tí wọ́n tẹ̀lé mi ní oúnjẹ, nítorí pé ó ti rẹ̀ wọ́n, ati pé à ń lé Seba ati Salimuna, àwọn ọba Midiani mejeeji lọ ni.”

6. Àwọn ìjòyè Sukotu dá a lóhùn, wọ́n ní, “Ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Seba ati Salimuna ni, tí a óo fi fún ìwọ ati àwọn ọmọ ogun rẹ ní oúnjẹ?”

7. Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Kò burú, nígbà tí OLUWA bá fi Seba ati Salimuna lé mi lọ́wọ́, ẹ̀gún ọ̀gàn aṣálẹ̀ ati òṣùṣú ni n óo fi ya ẹran ara yín.”

8. Ó kúrò níbẹ̀ lọ sí Penueli, ó sọ ohun kan náà fún wọn, ṣugbọn irú èsì tí àwọn ará Sukotu fún un ni àwọn ará Penueli náà fún un.

9. Ó sọ fún àwọn ará Penueli pé, “Nígbà tí mo bá pada dé ní alaafia n óo wó ilé ìṣọ́ yìí.”

10. Seba ati Salimuna wà ní ìlú Karikori pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn yòókù, gbogbo àwọn ọmọ ogun ìlà oòrùn tí wọ́n ṣẹ́kù kò ju nǹkan bí ẹẹdẹgbaajọ (15,000) lọ, nítorí pé àwọn tí wọ́n ti kú ninu àwọn ọmọ ogun wọn tí wọ́n ń lo idà tó ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000).

11. Ọ̀nà èrò tí ó wà ní ìlà oòrùn Noba ati Jogibeha ni Gideoni gbà lọ, ó lọ jálu àwọn ọmọ ogun náà láì rò tẹ́lẹ̀.

12. Seba ati Salimuna bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, ṣugbọn Gideoni lé àwọn ọba Midiani mejeeji yìí títí tí ó fi mú wọn. Jìnnìjìnnì bá dàbo gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 8