Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 20:23-30 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Wọ́n bá lọ sọkún níwájú OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n ní, “Ṣé kí á tún gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tí í ṣe àwọn arakunrin wa?”OLUWA dá wọn lóhùn pé kí wọ́n lọ gbógun tì wọ́n.

24. Àwọn ọmọ Israẹli bá tún lọ gbógun ti àwọn ọmọ ogun Bẹnjamini ní ọjọ́ keji.

25. Àwọn ará Bẹnjamini bá tún jáde láti Gibea ní ọjọ́ keji, wọ́n pa ọ̀kẹ́ kan ó dín ẹgbaa (18,000) eniyan ninu àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń fi idà jà.

26. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá lọ sí Bẹtẹli, wọ́n jókòó wọ́n sọkún níbẹ̀ níwájú OLUWA, wọ́n gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́; wọ́n sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia níwájú OLUWA.

27. Àwọn ọmọ Israẹli tún wádìí lọ́dọ̀ OLUWA, nítorí pé àpótí majẹmu Ọlọrun wà ní Bẹtẹli ní àkókò náà.

28. Finehasi ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni ló ń ṣe iṣẹ́ alufaa ní àkókò náà, àwọn ọmọ Israẹli tún bèèrè pé, “Ṣé kí á tún lọ gbógun ti àwọn ará Bẹnjamini tíí ṣe arakunrin wa àbí kí á dáwọ́ dúró?”OLUWA dá wọn lóhùn, ó ní, “Ẹ lọ gbógun tì wọ́n, nítorí pé, lọ́la ni n óo fi wọ́n le yín lọ́wọ́.”

29. Àwọn ọmọ Israẹli bá fi àwọn eniyan pamọ́ ní ibùba, yípo gbogbo Gibea.

30. Àwọn ọmọ Israẹli tún gbógun ti àwọn ọmọ Bẹnjamini ní ọjọ́ kẹta, wọ́n tò yípo Gibea bíi ti iṣaaju.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 20