Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 19:3-15 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Lẹ́yìn náà, ọkọ rẹ̀ dìde, ó lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó pada. Ọkunrin yìí mú iranṣẹ kan ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi meji lọ́wọ́. Nígbà tí ó dé ilé baba obinrin rẹ̀ yìí, tí baba iyawo rẹ̀ rí i, ó lọ pàdé rẹ̀ tayọ̀tayọ̀.

4. Baba obinrin náà rọ̀ ọ́ títí ó fi wà pẹlu wọn fún ọjọ́ mẹta; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì wà níbẹ̀.

5. Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu wọ́n fẹ́ máa lọ. Ṣugbọn baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ pé kí ó jẹ oúnjẹ díẹ̀ kí ó tó máa lọ, kí ó lè lágbára.

6. Àwọn ọkunrin mejeeji bá jókòó, wọ́n jẹ, wọ́n mu, lẹ́yìn náà ni baba ọmọbinrin yìí tún dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ kúkú dúró ní alẹ́ yìí kí o máa gbádùn ara rẹ.”

7. Nígbà tí ọkunrin náà gbéra, tí ó fẹ́ máa lọ, baba ọmọbinrin náà rọ̀ ọ́ títí tí ó tún fi dúró.

8. Nígbà tí ó di ọjọ́ karun-un, ọkunrin náà gbéra ní òwúrọ̀ kutukutu láti máa lọ, baba ọmọbinrin náà tún rọ̀ ọ́ pé kí ó fọkàn balẹ̀, kí ó di ìrọ̀lẹ́ kí ó tó máa lọ. Àwọn mejeeji bá jọ jẹun.

9. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́ ọkunrin náà ati obinrin rẹ̀ ati iranṣẹ rẹ̀ gbéra, wọ́n fẹ́ máa lọ; baba ọmọbinrin náà tún wí fún un pé, “Ṣé ìwọ náà rí i pè ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, jọ̀wọ́ dúró kí ó di ọ̀la. Ilẹ̀ ló ti ṣú yìí, dúró níhìn-ín kí o sì gbádùn ara rẹ, bí ó bá di ọ̀la kí ẹ bọ́ sọ́nà ní òwúrọ̀ kutukutu, kí ẹ sì máa lọ sílé.”

10. Ṣugbọn ọkunrin náà kọ̀, ó ní òun kò ní di ọjọ́ keji. Ó bá gbéra, ó ń lọ, títí tí wọ́n fi dé ibìkan tí ó dojú kọ Jebusi (tí wọ́n yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jerusalẹmu); àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀, obinrin rẹ̀ sì wà pẹlu rẹ̀.

11. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jebusi, ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, iranṣẹ rẹ̀ sọ fún un pé, “Jẹ́ kí á dúró ní ìlú àwọn ará Jebusi yìí kí á sì sùn níbẹ̀ lónìí.”

12. Ó dá a lóhùn, ó ní, “A kò ní wọ̀ ní ìlú àjèjì, lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, a óo kọjá lọ sí Gibea.”

13. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú wọnyi, kí á sì sùn ní Gibea tabi ní Rama.”

14. Wọ́n bá tún ń bá ìrìn àjò wọn lọ, oòrùn ti wọ̀ kí wọ́n tó dé Gibea, ọ̀kan ninu àwọn ìlú ẹ̀yà Bẹnjamini.

15. Wọ́n yà sibẹ, láti sùn di ọjọ́ keji. Wọ́n lọ jókòó ní ààrin ìgboro ìlú náà, nítorí pé, ẹnikẹ́ni kò gbà wọ́n sílé pé kí wọ́n sùn di ọjọ́ keji.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 19