Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 17:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Kò sí ọba ní ilẹ̀ Israẹli ní gbogbo àkókò náà, nítorí náà ohun tí ó bá tọ́ lójú olukuluku ni olukuluku ń ṣe.

7. Ọdọmọkunrin kan wà ní Juda, ará Bẹtilẹhẹmu, tí ó jẹ́ ọmọ Lefi láti inú ìdílé Juda, ó ń gbé ibẹ̀.

8. Ọdọmọkunrin náà kó kúrò ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda, láti lọ máa gbé ibikíbi tí ó bá ti rí ààyè. Bí ó ti ń lọ, ó dé ilé Mika ní agbègbè olókè ti Efuraimu.

9. Mika bá bi í pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”Ó dá a lóhùn pé, “Ọmọ Lefi, láti Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Juda ni mí, ibi tí n óo máa gbé ni mò ń wá kiri.”

10. Mika bá sọ fún un pè, “Máa gbé ọ̀dọ̀ mi, kí o sì jẹ́ baba ati alufaa fún mi, n óo máa san owó fadaka mẹ́wàá fún ọ lọ́dún. N óo máa dáṣọ fún ọ, n óo sì máa bọ́ ọ.”

11. Ọdọmọkunrin ọmọ Lefi náà gbà, láti máa gbé ọ̀dọ̀ Mika. Mika sì mú un gẹ́gẹ́ bí ọmọ.

12. Mika fi ọdọmọkunrin náà jẹ alufaa, ó sì ń gbé ilé Mika.

13. Mika bá dáhùn pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA yóo bukun mi, nítorí pé, ọmọ Lefi gan-an ni mo gbà gẹ́gẹ́ bí alufaa.”

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 17