Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 14:8-14 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni ó pada lọ láti lọ mú iyawo rẹ̀. Bí ó ti ń lọ, ó yà wo òkú kinniun tí ó pa, ó bá ọ̀wọ́ oyin ati afárá oyin lára rẹ̀.

9. Ó bá yọ́ ninu afárá oyin náà sí ọwọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí lá a bí ó ti ń lọ. Nígbà tí ó bá baba ati ìyá rẹ̀, ó fún wọn lá ninu rẹ̀; ṣugbọn kò sọ fún wọn pé ara òkú kinniun ni òun ti rẹ́ afárá oyin náà.

10. Baba rẹ̀ bá lọ sí ọ̀dọ̀ obinrin náà. Samsoni se àsè ńlá kan níbẹ̀, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọdọmọkunrin máa ń ṣe nígbà náà.

11. Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n mú ọgbọ̀n ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wá láti wà pẹlu rẹ̀.

12. Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fun yín, bí ẹ bá lè túmọ̀ àlọ́ náà láàrin ọjọ́ meje tí a ó fi se àsè igbeyawo yìí, n óo fun yín ní ọgbọ̀n ẹ̀wù funfun ati ọgbọ̀n aṣọ àríyá.

13. Ṣugbọn bí ẹ kò bá lè túmọ̀ àlọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóo fún mi ní ẹ̀wù funfun kọ̀ọ̀kan ati aṣọ àríyá kọ̀ọ̀kan.”Wọ́n bá dáhùn pé, “Pa àlọ́ rẹ kí á gbọ́.”

14. Ó bá pa àlọ́ náà fún wọn, ó ní,“Láti inú ọ̀jẹun ni nǹkan jíjẹ tií wá,láti inú alágbára sì ni nǹkan dídùn tií wá.”Wọn kò sì lè túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹta.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 14