Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amosi 5:10-15 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Wọ́n kórìíra ẹni tí ń bá ni wí lẹ́nu ibodè, wọ́n sì kórìíra ẹni tí ń sọ òtítọ́.

11. Ẹ̀ ń rẹ́ talaka jẹ, ẹ sì ń fi ipá gba ọkà wọn. Nítòótọ́, ẹ ti fi òkúta tí wọ́n dárà sí kọ́ ilé, ṣugbọn ẹ kò ní gbé inú wọn; ẹ ti ṣe ọgbà àjàrà dáradára, ṣugbọn ẹ kò ní mu ninu ọtí waini ibẹ̀.

12. Gbogbo ìwà àìdára yín ni mo mọ̀, mo sì mọ̀ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín ti tóbi tó, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fìyà jẹ olódodo, tí ẹ̀ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ẹ sì ń du àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn lẹ́nu ibodè.

13. Nítorí náà, ẹni tí ó bá gbọ́n yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní irú àkókò yìí, nítorí pé àkókò burúkú ni.

14. Ire ni kí ẹ máa wá, kì í ṣe ibi kí ẹ lè wà láàyè; nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun yóo wà pẹlu yín, bí ẹ ti jẹ́wọ́ rẹ̀.

15. Ẹ kórìíra ibi, kí ẹ sì fẹ́ ire, ẹ jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ lẹ́nu ibodè yín; bóyá OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun yóo ṣàánú fún àwọn ọmọ ilé Josẹfu yòókù.

Ka pipe ipin Amosi 5