Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 60:17-22 BIBELI MIMỌ (BM)

17. “Dípò bàbà, wúrà ni n óo mú wá.Dípò irin, fadaka ni n óo mú wá.Dípò igi, bàbà ni n óo mú wá.Dípò òkúta, irin ni n óo mú wá.N óo mú kí àwọn alabojuto yín wà ní alaafia,àwọn akóniṣiṣẹ́ yín yóo sì máa ṣe òdodo.

18. Kò tún ní sí ìró ìdàrúdàpọ̀ ní ilẹ̀ rẹ mọ́,kò sì ní sí ìdágìrì ati ìparun ní ibodè rẹ,o óo máa pe odi rẹ ní ìgbàlà,o óo sì máa pe ẹnubodè rẹ ní ìyìn.

19. “Kì í ṣe oòrùn ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní ọ̀sán,bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe òṣùpá ni yóo máa tan ìmọ́lẹ̀ fún ọ mọ́ ní òru:OLUWA ni yóo máa jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,Ọlọrun rẹ yóo sì jẹ́ ògo rẹ.

20. Oòrùn rẹ kò ní wọ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kò ní wọ òkùnkùn.Nítorí OLUWA ni yóo jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé fún ọ,ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóo sì dópin.

21. Gbogbo àwọn eniyan rẹ yóo jẹ́ olódodo,àwọn ni yóo jogún ilẹ̀ náà títí lae.Àwọn ni ẹ̀ka igi tí mo gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi,kí á baà lè yìn mí lógo.

22. Ìdílé tí ó rẹ̀yìn jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè,èyí tí ó sì kéré jùlọ yóo di orílẹ̀-èdè ńlá,Èmi ni OLUWA,kíákíá ni n óo ṣe é nígbà tí àkókò rẹ̀ bá tó.”

Ka pipe ipin Aisaya 60