Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 45:19-25 BIBELI MIMỌ (BM)

19. N kò sọ ọ́ níkọ̀kọ̀, ninu òkùnkùn.N kò sọ fún arọmọdọmọ Jakọbu pé:‘Ẹ máa wá mi ninu rúdurùdu.’Òtítọ́ ni Èmi OLUWA sọ.Ohun tí ó tọ́ ni mò ń kéde.”

20. OLUWA ní:“Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ wá,ẹ jọ súnmọ́ bí,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kù ninu àwọn orílẹ̀-èdè.Aláìlóye ni àwọn tí ń gbẹ́ ère igi lásán kiri,tí wọ́n sì ń gbadurasí oriṣa tí kò lè gbànìyàn là.

21. Ẹ sọ̀rọ̀ jáde, kí ẹ sì ro ẹjọ́ tiyín,jẹ́ kí wọ́n jọ gbìmọ̀ pọ̀.Ta ló sọ èyí láti ìgbà laelae?Ta ló kéde rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́?Ṣebí èmi OLUWA ni?Kò tún sí Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.Ọlọrun Olódodo ati Olùgbàlàkò tún sí ẹnìkan mọ́, àfi èmi.

22. “Ẹ yipada sí mi kí á gbà yín là,gbogbo ẹ̀yin òpin ayé.Nítorí èmi ni Ọlọrun,kò tún sí ẹlòmíràn mọ́.

23. Mo ti fi ara mi búra,mo sì fi ẹnu mi sọ̀rọ̀ pẹlu òtítọ́ inú,ọ̀rọ̀ tí kò ní yipada:‘Gbogbo orúnkún ni yóo wólẹ̀ fún mi,èmi ni gbogbo eniyan yóo sì búra pé àwọn óo máa sìn.’

24. “Nípa èmi nìkan ni àwọn eniyan yóo máa pé,‘Ninu OLUWA ni òdodo ati agbára wà.’Gbogbo àwọn tí ń bá a bínúyóo pada wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu ìtìjú.

25. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo ṣẹgun,wọn yóo sì ṣògo ninu OLUWA.

Ka pipe ipin Aisaya 45