Mo ti fi ara mi búra,mo sì fi ẹnu mi sọ̀rọ̀ pẹlu òtítọ́ inú,ọ̀rọ̀ tí kò ní yipada:‘Gbogbo orúnkún ni yóo wólẹ̀ fún mi,èmi ni gbogbo eniyan yóo sì búra pé àwọn óo máa sìn.’