Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 44:15-28 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Lẹ́yìn náà igi yìí di igi ìdáná: Eniyan óo gé ninu rẹ̀, yóo fi dáná yá; yóo gé ninu rẹ̀ yóo fi dáná oúnjẹ; yóo gé ninu rẹ̀, yóo fi gbẹ́ ère, yóo máa bọ ọ́. Eniyan á wá sọ igi lásán tí ó gbẹ́ di oriṣa, á sì máa foríbalẹ̀ fún un.

16. Yóo fi ìdajì rẹ̀ dáná, yóo fi se oúnjẹ, yóo fi se ẹran rẹ̀ pẹlu. Yóo jẹun, yóo jẹran, yóo yó; yóo tún yáná. Yóo ní, “Áà! Ooru mú mi nítorí mo rí iná yá.”

17. Yóo fi èyí tí ó kù gbẹ́ ère oriṣa rẹ̀, yóo máa foríbalẹ̀ fún un, yóo máa bọ ọ́, yóo máa gbadura sí i pé, “Gbà mí, nítorí ìwọ ni Ọlọrun mi.”

18. Wọn kò mọ nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni òye kò yé wọn. Nǹkankan ti bò wọ́n lójú kí wọn má baà lè ríran; ó sì ti sé wọn lọ́kàn kí òye má baà yé wọn.

19. Kò sí ẹni tí ó ronú wò, tabi tí ó ní ìmọ̀ tabi òye, láti wí pé: “Ìdajì igi yìí ni mo fi dáná tí mo fi se oúnjẹ, tí mo sì fi se ẹran tí mo jẹ. Kí ló wá dé tí n óo ṣe fi ìyókù gbẹ́ ère kí n máa bọ ọ́? Ṣé ìtì igi lásán ló yẹ kí n máa foríbalẹ̀ fún, kí n máa bọ?”

20. Kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń pe eérú ní oúnjẹ. Èrò ẹ̀tàn ti ṣì í lọ́nà, kò sì lè gba ara rẹ̀ kalẹ̀ tabi kí ó bi ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ irọ́ kọ́ ni ohun tí ó wà lọ́wọ́ mi yìí?”

21. Jakọbu, ranti àwọn nǹkan wọnyi,nítorí pé iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli.Èmi ni mo ṣẹ̀dá rẹ, iranṣẹ mi ni ọ́,n kò jẹ́ gbàgbé rẹ, Israẹli.

22. Mo ti ká àìdára rẹ kúrò bí awọsanma,mo ti gbá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ dànù bí ìkùukùu.Pada sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ pada.

23. Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLUWA ti ṣe é.Ẹ pariwo, ẹ̀yin ìsàlẹ̀ ilẹ̀.Ẹ kọrin, ẹ̀yin òkè ńlá, ìwọ igbó ati igi inú rẹ̀,nítorí OLUWA ti ra Jakọbu pada,yóo sì ṣe ara rẹ̀ lógo ní Israẹli.

24. Gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà rẹ wí,ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú oyún.Ó ní, “Èmi ni OLUWA, tí mo dá ohun gbogbo.Èmi nìkan ni mo tẹ́ ojú ọ̀run,tí mo sì dá ilẹ̀ ayé tẹ́,

25. èmi tí mo sọ àmì àwọn tí ń woṣẹ́ èké di asán,tí mo sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀.Mo yí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n pomo sì sọ ọgbọ́n wọn di òmùgọ̀.

26. Èmi tí mo jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ iranṣẹ mi,tí mo sì mú ìmọ̀ àwọn ikọ̀ mi ṣẹ,èmi tí mo wí fún Jerusalẹmu pé,‘Àwọn eniyan yóo máa gbé inú rẹ,’tí mo sì wí fún àwọn ìlú Juda pé,‘A óo tún odi yín mọ,n óo sì tún yín kọ́.’

27. Èmi tí mo pàṣẹ fún agbami òkun pé, ‘Gbẹ!n óo mú kí àwọn odò rẹ gbẹ;’

28. èmi tí mo sọ fún Kirusi pé:‘Ìwọ ni ọba tí n óo yàn tí yóo mú gbogbo ìpinnu mi ṣẹ;’tí mo sọ fún Jerusalẹmu pé:‘A óo tún odi rẹ̀ mọ,’tí mo sì sọ fún Tẹmpili pé,‘A óo tún fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀.’ ”

Ka pipe ipin Aisaya 44