Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 42:16-24 BIBELI MIMỌ (BM)

16. “N óo darí àwọn afọ́jú,n óo mú wọn gba ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí,n óo tọ́ wọn sọ́nà,ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀ rí.N óo sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀ níwájú wọn,n óo sì sọ àwọn ibi tí ó rí pálapàla di títẹ́jú.N óo ṣe àwọn nǹkan,n kò sì ní kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

17. A óo ká àwọn tí ó gbójú lé ère lọ́wọ́ kò,ojú yóo sì tì wọ́n patapataàwọn tí ń wí fún ère gbígbẹ́ pé:‘Ẹ̀yin ni Ọlọrun wa.’ ”OLUWA ní:

18. “Gbọ́, ìwọ adití,sì wò ó, ìwọ afọ́jú, kí o lè ríran.

19. Ta ni afọ́jú, bíkòṣe iranṣẹ mi?Ta sì ni adití, bíkòṣe ẹni tí mo rán níṣẹ́?Ta ni ó fọ́jú tó ẹni tí mo yà sọ́tọ̀,tabi ta ni ojú rẹ̀ fọ́ tó ti iranṣẹ OLUWA?

20. Ó ń wo ọpọlọpọ nǹkan, ṣugbọn kò ṣe akiyesi wọn.Etí rẹ̀ là sílẹ̀,ṣugbọn kò gbọ́ràn.”

21. Ó wu OLUWA láti gbé òfin rẹ̀ gaati láti ṣe é lógo nítorí òdodo rẹ̀.

22. Ṣugbọn a ti ja àwọn eniyan wọnyi lólè,a sì ti kó wọn lẹ́rù,a ti sé gbogbo wọn mọ́ inú ihò ilẹ̀,a sì ti fi wọ́n pamọ́ sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n.A fogun kó wọn, láìsí ẹni tí yóo gbà wọ́n sílẹ̀,a kó wọn lẹ́rú, láìsí ẹnikẹ́ni tí yóo sọ pé:“Ẹ dá wọn pada.”

23. Èwo ninu yín ló fetí sí èyí,tabi tí yóo farabalẹ̀ gbọ́ nítorí ẹ̀yìn ọ̀la?

24. Ta ló fa Jakọbu lé akónilẹ́rù lọ́wọ́,ta ló sì fa Israẹli lé àwọn ọlọ́ṣà lọ́wọ́?Ṣebí OLUWA tí a ti ṣẹ̀ ni,ẹni tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀;tí wọn kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́.

Ka pipe ipin Aisaya 42