Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 34:9-17 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Àwọn odò ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà,erùpẹ̀ rẹ̀ yóo di imí ọjọ́;ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà tí ń jó bùlàbùlà.

10. Yóo máa jó tọ̀sán-tòru, kò ní kú,yóo máa rú èéfín sókè títí lae.Yóo di aṣálẹ̀ láti ìrandíran,ẹnikẹ́ni kò ní gbabẹ̀ kọjá mọ́ títí lae.

11. Àṣá ati òòrẹ̀ ni yóo fi ibẹ̀ ṣe ilé,òwìwí ati ẹyẹ kannakánná ni yóo máa gbé ibẹ̀.OLUWA yóo ta okùn ìdàrúdàpọ̀ lé e lórí,yóo sì na ọ̀pá ìdàrúdàpọ̀ lé àwọn ìjòyè rẹ̀ lórí.

12. “Kò sí Ilẹ̀ Ọba Mọ́” ni a óo máa pè é.Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo parẹ́.

13. Ẹ̀gún yóo hù ninu ààfin rẹ̀,ẹ̀gún òṣùṣú ati ẹ̀gún ọ̀gàn yóo hù ninu àwọn ìlú olódi rẹ̀.Wọn yóo di ibùgbé fún àwọn ọ̀fàfà ati ẹyẹ ògòǹgò,

14. àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò yóo jọ máa gbé ibẹ̀,àwọn ewúrẹ́ igbó yóo máa ké pe ara wọn.Iwin yóo rí ibi máa gbé,yóo sì rí ààyè máa sinmi níbẹ̀.

15. Òwìwí yóo pa ìtẹ́ sibẹ, tí yóo máa yé sí.Yóo pamọ, yóo ràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀,yóo sì máa tọ́jú wọn níbẹ̀.Àwọn àṣá yóo péjọ sibẹ,olukuluku wọn, pẹlu ekeji rẹ̀.

16. Ẹ lọ wá inú ìwé OLUWA,kí ẹ ka ohun tí ó wà níbẹ̀.Kò sí ọ̀kan ninu àwọn wọnyi tí kò ní sí níbẹ̀,kò sí èyí tí kò ní ní ẹnìkejì.Nítorí OLUWA ni ó pàṣẹ bẹ́ẹ̀,ẹ̀mí rẹ̀ ni ó sì kó wọn jọ.

17. Ó ti ṣẹ́ gègé fún wọn,ó ti fi okùn wọ̀n ọ́n kalẹ̀ fún wọn.Àwọn ni wọn óo ni ín títí lae,wọn óo sì máa gbé ibẹ̀ láti ìrandíran.

Ka pipe ipin Aisaya 34