Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 11:7-12 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Mààlúù ati ẹranko beari yóo jọ máa jẹun pọ̀,àwọn ọmọ wọn yóo jọ máa sùn pọ̀,kinniun yóo sì máa jẹ koríko bí akọ mààlúù.

8. Ọmọ ọmú yóo máa ṣeré lórí ihò paramọ́lẹ̀,ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmúyóo máa fi ọwọ́ bọ inú ihò ejò.

9. Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́,tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi.Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayébí omi ṣe kún gbogbo inú òkun.

10. Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo.

11. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo na ọwọ́ rẹ̀ lẹẹkeji, yóo ra àwọn eniyan rẹ̀ yòókù pada ní oko ẹrú, láti Asiria, ati Ijipti, láti Patosi ati Etiopia, láti Elamu ati Ṣinari, láti Amati ati àwọn erékùṣù òkun.

12. Yóo gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,yóo kó àwọn Israẹli tí a ti patì jọ.Yóo ṣa àwọn ọmọ Juda tí wọ́n fọ́nká jọ,láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé.

Ka pipe ipin Aisaya 11