Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 11:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese,ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀.

2. Ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé e,ẹ̀mí ọgbọ́n ati òye,ẹ̀mí ìmọ̀ràn ati agbára,ẹ̀mí ìmọ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA.

3. Ìbẹ̀rù OLUWA ni yóo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀kì í ṣe ohun tí ó fojú rí,tabi èyí tí ó fi etí gbọ́ ni yóo fi ṣe ìdájọ́.

4. Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka,yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀,yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán,yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi.

5. Òdodo ni yóo fi ṣe àmùrè ìgbàdí rẹ̀,yóo sì fi òtítọ́ ṣe àmùrè ìgbànú rẹ̀.

6. Ìkookò yóo máa bá ọ̀dọ́ aguntan gbé,àmọ̀tẹ́kùn yóo sùn sílẹ̀ pẹlu ọmọ ewúrẹ́,ọmọ mààlúù, ati kinniun, ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa yóo jọ máa gbé pọ̀,ọmọ kékeré yóo sì máa kó wọn jẹ.

7. Mààlúù ati ẹranko beari yóo jọ máa jẹun pọ̀,àwọn ọmọ wọn yóo jọ máa sùn pọ̀,kinniun yóo sì máa jẹ koríko bí akọ mààlúù.

8. Ọmọ ọmú yóo máa ṣeré lórí ihò paramọ́lẹ̀,ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmúyóo máa fi ọwọ́ bọ inú ihò ejò.

9. Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́,tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi.Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayébí omi ṣe kún gbogbo inú òkun.

10. Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo.

11. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo na ọwọ́ rẹ̀ lẹẹkeji, yóo ra àwọn eniyan rẹ̀ yòókù pada ní oko ẹrú, láti Asiria, ati Ijipti, láti Patosi ati Etiopia, láti Elamu ati Ṣinari, láti Amati ati àwọn erékùṣù òkun.

Ka pipe ipin Aisaya 11