orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Títù 2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àwọn Èkọ́ Tí A Gbọ́dọ̀ Kọ́ Ní Onírúurú Àkójọpọ̀

1. Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ máa kọ́ni ní ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro lórí ìgbé ayé onígbàgbọ́ tòótọ́.

2. Kọ́ àwọn àgbà ọkùnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìrònú àti láti jẹ́ ẹni àpọ́nlé àti ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Wọn gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí ó jinlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, nínú ìfẹ́ àti nínú ìpamọ́ra.

3. Bákan náà, ni kí ó kọ́ àwọn àgbà obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti kọ́ bí àátí gbé ìgbé-ayé ẹni-ọ̀wọ̀, wọn kò gbọdọ̀ jẹ́ afọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ tàbí olùfẹ́ wáìnì mímú, ṣùgbọ́n wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ olùkọ́ ohun rere.

4. Nípa èyí, wọ́n yóò lè máa kọ́ àwọn òdóbìnrin láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọkọ wọn àti àwọn ọmọ wọn,

5. láti jẹ́ ẹni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti ọlọ́kàn mímọ́, kí wọ́n máa ṣe ojúse wọn nínú ilé, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ onínú rere, kí wón sì máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọ́n, kí ẹnikẹ́ni máa baà sọ̀rọ̀ òdì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

6. Bákan náà, rọ àwọn ọ̀dọ́ ọkùnrin láti kó ara wọn ni ìjánu.

7. Nínú ohun gbogbo fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí alápẹẹrẹ ohun rere. Nínú ẹ̀kọ́ rẹ fi apẹẹrẹ ìwà pípé hàn, ẹni tó kún ojú òsùnwọ̀n

8. jẹ́ ẹni tó jáfáfà nínú ọ̀rọ̀ sísọ, ẹni tí kò see tanù, kí ojú kò lé tí àwọn alátakò rẹ̀ nígbà tí wón kò bá rí ohun búburú sọ nípa rẹ̀.

9. Kọ́ àwọn ẹrú láti se ìgbọ́ran sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu,

10. wọn kò gbọdọ̀ jàwọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wón jẹ́ ẹni tó seé gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere.

11. Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó mú ìgbàlà wà ti fara hàn fún gbogbo ènìyàn.

12. Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a gbé ìgbé ayé ìkóra-ẹni-ní-ìjánu, ìdúrósinsin àti ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsínsìnyìí,

13. bí a ti ń wọ̀nà fún ìrètí tó ní bùkún, èyí ń ní ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jésù Kírísìtì.

14. Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpàda kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún iní ohun tìkara rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere.

15. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni kí ìwọ kí ó máa kọ wọn. Gba ni níyànjú kí ó sì máa fi gbogbo àṣẹ bániwí. Máe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó gàn ọ́.