Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 8:25-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ṣùgbọ́n bí àwa bá ń retí èyí tí àwa kò rí, ǹjẹ́ àwa ń fi sùúrù dúró dè é.

26. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ: ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkáara rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa.

27. Ẹni tí ó sì ń wá ọkàn wò, ó mọ ohun ti inú ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.

28. Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń siṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀.

29. Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, u kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrin àwọn arákùnrin púpọ̀

30. Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di “aláìjẹ̀bi” lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kírísítì kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.

31. Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa?

32. Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti yọ̀ǹda ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le sòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí?

33. Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dárí jì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀.

34. Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Ǹjẹ́ Kírísítì Yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ó kú fún wa tó sì tún jí ǹ de, nisínsin yìí, Òun jókòó ní ibi tí ó ga jùlọ tí ó lọ́lá, tí ó fara ti Ọlọ́run. Òun sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa lọ́run níbẹ̀.

35. Ta ni ó tilẹ̀ le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kírísítì? Nígbà tí wàhálà tàbí ìdàmú bá dé, nígbà tí wọ́n bá já wa lulẹ̀ tàbí pa wá. Ṣé nítórí pé Ọlọ́run kò fẹ́ràn wa mọ́ ni àwọn nǹkan wọ̀nyí yóò fi sẹlẹ̀ sí wa? Àti pé, Bí ebi bá ń pa wá, tàbí kò sí kọ́bọ̀ lọ́wọ́, tàbí a wà nínú ìsòro, tàbí ikú dẹ́rù bà wá, ǹjẹ́ Ọlọ́run ti fi wá sílẹ̀ bí?

36. Bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí ìwé mímọ́ sọ fún wa pé:“Nítorí yín àwa ní láti múra tan fún ikú nígbàkúgbà.Àwa dàbí àgùntàn tí ń dúró de pípa.”

37. Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìṣẹ́gun ni ti wa nípaṣẹ̀ Kírísítì, ẹni tí ó fẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó sì fi fún wa.

38. Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kò sí ohunkóhun tó lè yà wá nínú ìfẹ́ rẹ̀. Kì í se ikú tàbí ìyè. Àwọn ańgẹ́lì àti gbogbo agbára ọ̀run àpáàdì fún raarẹ̀ kò le ya ìfẹ́ Ọlọ́run kúrò lọ́dọ̀ wa. Ìbẹ̀rù fún wa lónìí, wàhálà nípa ti ọjọ́ ọ̀la.

Ka pipe ipin Róòmù 8