Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Róòmù 15:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má si ṣe ohun tí ó wu ara wa.

2. Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró.

3. Nítorí Kírísítì pàápàá kò ṣe ohun tí ó wu ara rẹ̀, ṣùgbọ́n, bí a ti kọ ọ́ pé: “Àwọn ẹni tí ń tàbùkù rẹ ń tàbùkù mi pẹ̀lú.”

4. Nítorí ohun gbogbo tí a kọ nígbà àtijọ́ ni a kọ láti fi kọ́ wa, kí àwa lè ní ìrètí nípa sùúrù àti ìtùnú èyí tí ó wá láti inú ìwé mímọ́.

5. Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin ní ẹ̀mí ìrẹ́pọ̀ láàrin ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jésù Kírísítì,

6. kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì.

7. Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kírísítì ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run.

8. Mo sì wí pé, a rán Kírísítì láti ṣe ìránṣẹ́ àwọn tí se Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀,

9. kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:“Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrin àwọn aláìkọlà,Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.”

10. Ó sì tún wí pé,“Ẹ̀yin aláìkọlà, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.”

11. Àti pẹ̀lú,“Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin aláìkọlà;ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.”

12. Àìṣáyà sì tún wí pé,“Gbòngbò Jésè kan ń bọ̀ wá,òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn aláìkọlà;Àwọn aláìkọlà yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”

13. Njẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yín ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrétí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

14. Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, è pé ní ìmọ̀, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín.

15. Mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fifún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run

16. láti jẹ́ ìránsẹ́ Kírísìtì Jésù láàrin àwọn aláìkọlà láti polongo ìyìn rere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúse àlùfáà, kí àwọn aláìkọlà lè jẹ́ ẹbọ-ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí mímọ́ yà sí mímọ́.

17. Nítorí náà, mo ní ìsògo nínú Kírísítì Jésù nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run.

Ka pipe ipin Róòmù 15