Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 21:15-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kigbé nínú tẹ́ḿpìlì pé, “Hòsánà fún ọmọ Dáfídì,” inú bí wọn.

16. Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?”Jésù sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,”“Àbí ẹ̀yin kò kà á pé ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ-ọmú,ni a ó ti máa yìn mí’?”

17. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀, ó lọ sí Bẹ́tánì. Níbẹ̀ ni ó dúró ní òru náà.

18. Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á.

19. Ó sì ṣàkíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lẹ́bàá ojú ọ̀nà, ó sì lọ wò ó bóyá àwọn èso wà lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ kan, ewé nìkan ni ó wà lórí rẹ̀. Nígbà náà ni ó sì wí fún igi náà pé, “Kí èso má tún so lórí rẹ mọ́.” Lójú kan náà igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì gbẹ.

20. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí èyí, ẹnú yà wọn, wọ́n béèrè pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ kíákíà?”

21. Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin bá lè ní ìgbàgbọ́ láì síyè méjì, nígbà náà ẹ̀yin yóò lè ṣe irú tí a se sí igi ọ̀pọ̀tọ́, Ẹ̀yin yóò lè sọ fún òkè yìí pé, ‘Yí ipò padà sínú òkun,’ yóò sì ríbẹ́ẹ̀.

22. Bí ẹ̀yin bá gbàgbọ́, ẹ̀yin lè rí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè nínú àdúrà gbà.”

Ka pipe ipin Mátíù 21