Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 2:2-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Wọ́n si béèrè pé, “Níbo ni ẹni náà tí a bí tí í ṣe ọba àwọn Júù wà? Àwa ti rí ìràwọ̀ rẹ̀ ní ìlà-oòrun, a sì wá láti foríbalẹ̀ fún un.”

3. Nígbà tí ọba Hẹ́rọ́dù sì gbọ́ èyí, ìdáàmú bá a àti gbogbo àwọn ara Jerúsálémù pẹ̀lú rẹ̀

4. Nígbà tí ó sì pe àwọn olórí àlùfàá àti àwọn olùkọ́ òfin jọ, ó bi wọ́n léèrè níbi ti a ó gbé bí Kírísítì?

5. Wọ́n sì wí pé, “Ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà, èyí ni ohun tí wòlíì ti kọ ìwé rẹ̀ pé:

6. “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ní ilẹ̀ Jùdíà,ìwọ kò kéré jù láàrin àwọn ọmọ aládé Jùdíà;nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde,Ẹni ti yóò ṣe àkóso lórí Ísírẹ́lì, àwọn ènìyàn mi.’ ”

7. Nígbà náà ni Hérọ́dù ọba pe àwọn amòye náà sí ìkọ̀kọ̀, ó sì wádìí ni ọwọ́ wọn, àkókò náà gan-an tí wọ́n kọ́kọ́ rí ìràwọ̀.

8. Ó sì rán wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sì wí pé, “Ẹ lọ ṣe ìwádìí fínnífínní ní ti ọmọ náà tí a bí. Lẹ́yìn tí ẹ bá sì rí i, ẹ padà wá sọ fún mi, kí èmi náà le lọ foríbalẹ̀ fún un.”

9. Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba, wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n, sì wò ó, ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí láti ìhà ìlà-oòrùn wá, ó ṣáájú wọn, títítí ó fi dúró lókè ibi tí ọmọ náà gbé wà.

10. Nígbà tí wọ́n sì rí ìràwọ̀ náà, ayọ̀ kún ọkàn wọn.

11. Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n forí balẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ẹrù wọn, wọ́n sì ta Jésù lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjíà.

12. Nítorí pé Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wọn ní ojú àlá pé kí wọ́n má ṣe padà tọ Hérọ́dù lọ mọ́, wọ́n gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ìlú wọn.

13. Nígbà tí wọn ti lọ, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Jósẹ́fù ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sá lọ sí Éjíbítì. Dúró níbẹ̀ títítí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Hẹ́rọ̀dù yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ-ọwọ́ náà.”

14. Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Éjíbítì,

15. ó sì wà níbẹ̀ títítí Hẹ́rọ́dù fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé: “Mo pe ọmọ mi jáde láti Éjíbítì wá.”

16. Nígbà tí Hẹ́rọ̀dù rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà.

Ka pipe ipin Mátíù 2