Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 10:17-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. “Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nítorí wọn yóò fi yín le àwọn ìgbìmọ̀ ìgbéríko lọ́wọ́ wọn yóò sì nà yín nínú sínágọ́gù.

18. Nítorí orúkọ mi, a ó mú yín lọ ṣíwájú àwọn baálẹ̀ àti àwọn ọba, bí ẹlẹ́rìí sí wọn àti àwọn aláìkọlà.

19. Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́. Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín,

20. Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.

21. “Ọmọ-ìyá méjì yóò ṣe ikú pa ara wọ́n. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò sọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n.”

22. Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà.

23. Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sá lọ sì ìlú kejì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Ísírẹ́lì já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé.

24. “Akẹ́kọ̀ọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ-ọ̀dọ̀ kì í ju ọ̀gá rẹ̀ lọ.

25. Ó tọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láti dà bí olùkọ́ rẹ̀ àti fún ọmọ-ọ̀dọ̀ láti rí bí ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá pe baálé ilé ní Béélísébúbù, mélòó mélòó ni ti àwọn ènìyàn ilé rẹ̀!

26. “Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, nítorí kò sí ohun to bò tí kò níí fara hàn, tàbí ohun tó wà ní ìkọ̀kọ̀ tí a kò ní mọ̀ ni gbangba.

27. Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé.

28. Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lé pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa Ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run apáàdì.

29. Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Ṣíbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lulẹ̀ lẹ́yìn Baba yin.

30. Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé.

Ka pipe ipin Mátíù 10