Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 10:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jésù sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn àrùn àti àìsàn gbogbo.

2. Orúkọ àwọn àpósítélì méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí: ẹni àkọ́kọ́ ni Símónì ẹni ti a ń pè ni Pétérù àti arákùnrin rẹ̀ Ańdérù, Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti arákùnrin rẹ̀ Jòhánù.

3. Fílípì àti Bátólómíù; Tómásì àti Mátíù agbowó òde; Jákọ́bù ọmọ Álíféù àti Tádéù;

4. Símónì ọmọ ẹgbẹ́ Sílíọ́tì, Júdásì Ísíkáríọ́tù, ẹni tí ó da Jésù.

5. Jésù ran àwọn méjèèjìla yìí jáde, pẹ̀lú àṣẹ báyìí pé: “Ẹ má ṣe lọ sì àárín àwọn aláìkọlà tàbí wọ̀ èyíkèyìí ìlú àwọn ará Samáríà

6. Ẹ kúkú tọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí ó nù lọ.

7. Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé: ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’

8. Ẹ máa ṣe ìwòṣan fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn okú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí-èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbàá, ọ̀fẹ́ ni kú ẹ fi fún ni.

9. Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín;

10. Ẹ má ṣe mú àpo fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un.

11. “Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títítí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀.

12. Nígbà tí ẹ̀yin bá sì wọ ilé kan, ẹ kí i wọn.

13. Bí ilé náa bá sì yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó bà sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó padà sọ́dọ̀ yín.

14. Bí ẹnikẹ́ni tí kò bá sì gbà yín, tàbí tí kò gba ọ̀rọ̀ yín, ẹ gbọn eruku ẹ̀ṣẹ̀ yín sílẹ̀ tí ẹ bá ń kúrò ní ilé tàbí ìlú náà.

Ka pipe ipin Mátíù 10