Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 8:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nítori náà, ó pàsẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi búrédì méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀.

7. Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jésù tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọ́n fún àwọn ènìyàn náà.

8. Gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn náà ló jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn. Lẹ́yìn èyí wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún.

9. Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4000) ènìyàn, ó sì rán wọn lọ.

10. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jésù wọ inú ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dálímánútà.

11. Àwọn Farisí tọ Jésù wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Láti dán an wò, wọ̀n bèèrè fún àmì láti ọ̀run.

12. Jésù mí kanlẹ̀, nígbà tí ó gbọ́ ìbéèrè wọn. Ó sì dáhùn wí pé, “Èéṣe tí ìran yìí fi ń wá àmì? Lóòtọ́ ni mo sọ fún un yín kò si àmì tí a ó fi fún ìran yín?”

13. Nígbà náà ni ó padà sínú ọkọ̀ ojú omi ó fi àwọn ènìyàn sílẹ̀, ó sì rékọjá sí apákejì òkun náà.

14. Sùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbàgbé láti mú búrédì tí yóò tó wọn ọ́n jẹ lọ́wọ́. Ẹyọ ìṣù búrédì kan ṣoṣo ni ó wà nínú ọkọ̀ wọn.

15. Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jésù kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó ń mú búrẹ́dì wú àwọn Farisí àti ti Hẹ́rọ́dù.”

16. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú èyí láàrin ara wọn wí pé, “Torí pé a kò mú búrédì lọ́wọ́ ni?”

17. Jésù mọ ohun tí wọ́n sọ láàrin ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èése ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú búrẹ́dì lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsí i sì títí di ìsinyìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni?

18. Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹyín ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí?

19. Nígbà ti mo bu ìṣù búrẹ́dì márùn ún fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣà jọ?”Wọ́n wí pé, “Méjìlá.”

20. “Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn?”Wọ́n dáhùn pé, “Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje.”

Ka pipe ipin Máàkù 8